Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Select Readings: Nature's testimony
Àwọn ẹsẹ nípa Nature's testimony
Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ, àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà.
Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin, bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá.
Ènìyàn ni ó fi òpin si òkùnkùn, ó sì ṣe àwárí ìṣúra láti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo.
Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jì sí àwọn tí ń gbé òkè, àwọn tí ẹsẹ̀ ènìyàn gbàgbé wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀, wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn.
Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá, àti ohun tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni ó yí padà bi iná;
òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta safire, o sì ní erùpẹ̀ wúrà.
Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀, àti ojú gúnnugún kò rí i rí.
Àwọn ẹranko agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí.
Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta, ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá.
Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta, ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.
Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún àkúnya, ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀.
Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe?
Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”; omi òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.”
A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òsùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.
A kò le è fi wúrà Ofiri, tàbí òkúta óníkìsì iyebíye, tàbí òkúta safire díye lé e.
Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀.
A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi; iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ.
Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.
Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá? Tàbí níbo ni òye ń gbé?
A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo, ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.
Ibi ìparun àti ikú wí pé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.
Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀, òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé.
Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé, ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,
láti dà òsùwọ̀n fún afẹ́fẹ́, ó sì fi òsùwọ̀n wọ́n omi.