Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Select Readings: The glory of God

11 ẹsẹ · 47 abala

Àwọn ẹsẹ nípa The glory of God

  1. Saamu ti Dafidi. Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.

  2. Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀; sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

  3. Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá; Ọlọ́run ògo sán àrá, Olúwa san ara.

  4. Ohùn Olúwa ní agbára; ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.

  5. Ohùn Olúwa fa igi kedari; Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.

  6. Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù, àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.

  7. Ohùn Olúwa ń ya bí ọwọ́ iná mọ̀nà.

  8. Ohùn Olúwa ń mi aginjù. Olúwa mi aginjù Kadeṣi.

  9. Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí, ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò. Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé, “Ògo!”

  10. Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi; Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.

  11. Kí Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀; bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.