Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Select Readings: The new song

9 ẹsẹ · 47 abala

Àwọn ẹsẹ nípa The new song

  1. Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa, nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀ o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un

  2. Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀ o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.

  3. Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli; gbogbo òpin ayé ni ó ti rí iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.

  4. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé, ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn,

  5. ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,

  6. pẹ̀lú ìpè àti fèrè ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.

  7. Jẹ́ kí òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

  8. Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́, ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;

  9. ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa, nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.