Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Select Readings: Mary's Magnificat
Àwọn ẹsẹ nípa Mary's Magnificat
Maria sì dáhùn, ó ní: “Ọkàn mi yin Olúwa lógo.
Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
Nítorí tí ó síjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀. Sá wò ó, láti ìsinsin yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi; Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.
Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, láti ìrandíran.
Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀; o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.
Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn, o sì gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ lékè.
Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebi ń pa ó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.
Ó ti ran Israẹli ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́, ní ìrántí àánú rẹ̀;
sí Abrahamu àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa, àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”
Maria sì jókòó tì Elisabeti níwọ̀n oṣù mẹ́ta, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀.