Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Select Readings

802 ẹsẹ · 47 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá; iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá, ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.

  2. Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá; àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.

  3. Ó gun orí kérúbù, ó sì fò; ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.

  4. Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run.

  5. Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná

  6. Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá; Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná.

  7. Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká, ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.

  8. A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn òkun hàn, a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé nípa ìbáwí rẹ, Olúwa, nípa fífún èémí ihò imú rẹ.

  9. Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú; Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn.

  10. Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára, láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá, ti ó lágbára jù fún mi.

  11. Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi; ṣùgbọ́n Olúwa ni alátìlẹ́yìn mi.

  12. Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá; Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi.

  13. Saamu ti Dafidi. Olúwa ni olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.

  14. Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù, Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́,

  15. Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò. Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.

  16. Bí mo tilẹ̀ ń rìn láàrín àfonífojì òjìji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan, nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ, wọ́n ń tù mí nínú.

  17. Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi ní ojú àwọn ọ̀tá à mi. Ìwọ ta òróró sí mi ní orí; ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.

  18. Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo, èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa títí láéláé.

  19. Ti Dafidi. Saamu. Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;

  20. nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkun ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

  21. Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ? Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?

  22. Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun, ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán tí kò sì búra èké.

  23. Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa, àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.

  24. Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.

  25. Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà; kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé! Kí ọba ògo le è wọlé.