Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Peter

292 ẹsẹ · 35 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa sì yípadà, ó wo Peteru. Peteru sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.”

  2. Peteru sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.

  3. Nígbà náà ni Peteru dìde, ó súré lọ sí ibojì; nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnra wọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe.

  4. Wọn si wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Simoni!”

  5. Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jesu. Jesu sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Peteru).

  6. Nígbà náà ni Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa ó lọ? Ìwọ ni ó ni ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.

  7. Àwa sì ti gbàgbọ́, a sì mọ̀ pé ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”

  8. Simoni Peteru wí fún un pé, “Olúwa, níbo ni ìwọ ń lọ?” Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí èmi ń lọ, ìwọ kì yóò lè tẹ̀lé mí nísinsin yìí; ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ̀ mí lẹ́yìn ní ìkẹyìn.”

  9. Peteru wí fún un pé, “Olúwa èéṣe tí èmi kò fi le tọ̀ ọ́ lẹ́hìn nísinsin yìí? Èmi ó fi ẹ̀mí mi lélẹ̀ nítorí rẹ.”

  10. Jesu dalóhùn wí pé, “Ìwọ ó ha fi ẹ̀mí rẹ lélẹ̀ nítorí mi? Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, àkùkọ kì yóò kọ, kí ìwọ kí ó tó ṣẹ́ mi nígbà mẹ́ta!

  11. Simoni Peteru sì ń tọ Jesu lẹ́yìn, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn kan: ọmọ-ẹ̀yìn náà jẹ́ ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà, ó sì bá Jesu wọ ààfin olórí àlùfáà lọ.

  12. Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà wí fún Peteru pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí?” Ó wí pé, “Èmi kọ́.”

  13. Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn aláṣẹ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí ti òtútù mú, wọ́n sì ń yáná, Peteru sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná.

  14. Ṣùgbọ́n Simoni Peteru dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?” Ó sì sẹ́, wí pé, “Èmi kọ́.”

  15. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Peteru gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, “Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá?”

  16. Peteru tún sẹ́: lójúkan náà àkùkọ sì kọ.

  17. Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Simoni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn wá, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”

  18. Nígbà náà ni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà jáde, wọ́n sì wá sí ibojì.

  19. Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn náà sì sáré ya Peteru, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì.

  20. Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀.

  21. Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀.

  22. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu tún fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ létí Òkun Tiberia; báyìí ni ó sì farahàn.

  23. Simoni Peteru, àti Tomasi tí a ń pè ní Didimu, àti Natanaeli ará Kana ti Galili, àti àwọn ọmọ Sebede, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀.

  24. Simoni Peteru wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun.

  25. Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, Jesu dúró létí Òkun, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni.