Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Peter: His denial of Jesus, and his repentance

27 ẹsẹ · 35 abala

Àwọn ẹsẹ nípa His denial of Jesus, and his repentance

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lákòókò yìí, bí Peteru ti ń jókòó ní àgbàlá, ọmọbìnrin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Ìwọ wà pẹ̀lú Jesu ti Galili.”

  2. Ṣùgbọ́n Peteru sẹ̀ ní ojú gbogbo wọn pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ohun tí ẹ ń sọ nípa rẹ̀.”

  3. Lẹ́yìn èyí, ní ìta ní ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin mìíràn tún rí i, ó sì wí fún àwọn tí ó dúró yíká pé, “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jesu ti Nasareti.”

  4. Peteru sì tún sẹ́ lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú ìbúra pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ọkùnrin náà rárá.”

  5. Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó ń dúró níbi ìran yìí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún Peteru pé, “Lóòótọ́, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, àwa mọ̀ ọ́n. Èyí sì dá wa lójú nípa àmì ohùn rẹ̀ tí ó ń ti ẹnu rẹ jáde.”

  6. Peteru sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í búra ó sì fi ara rẹ̀ ré wí pé, “Mo ní èmi kò mọ ọkùnrin yìí rárá.” Lójúkan náà àkùkọ sì kọ.

  7. Nígbà náà ni Peteru rántí nǹkan tí Jesu ti sọ pé, “Kí àkùkọ tó ó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.” Òun sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.

  8. Ní àkókò yìí Peteru wà ní ìsàlẹ̀ inú àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Nínú àgbàlá yìí, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àlùfáà àgbà kíyèsi í tí Peteru ń yáná.

  9. Nígbà tí ó rí Peteru tí ó ti yáná, Ó tẹjúmọ́ ọn. Ó sì sọ gbangba pé, “Ìwọ pàápàá wà pẹ̀lú Jesu ara Nasareti.”

  10. Ṣùgbọ́n Peteru sẹ́, ó ni, “N kò mọ Jesu náà rí; ohun tí ó ń sọ yìí kò tilẹ̀ yé mi.” Peteru sì jáde lọ sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Àkùkọ sì kọ.

  11. Ọmọbìnrin náà sì tún rí Peteru. Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀. Ó ní, “Ọkùnrin yìí gan an jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu.”

  12. Ṣùgbọ́n Peteru tún sẹ́. Nígbà tí ó sí túnṣe díẹ̀ sí i, àwọn tí wọ́n dúró lẹ́gbẹ́ Peteru wá wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni, ọ̀kan ní ara wọn ni ìwọ í ṣe. Nítorí ará Galili ni ìwọ, èdè rẹ sì jọ bẹ́ẹ̀.”

  13. Nígbà náà ni Peteru bẹ̀rẹ̀ sí í sẹ́ ó sì ń búra, ó ni, “N kò mọ ẹni ti ẹ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí rí!”

  14. Lójúkan náà tí àkùkọ yìí kọ lẹ́ẹ̀kejì Peteru rántí ọ̀rọ̀ Jesu fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀méjì, ìwọ yóò sẹ́ mí nígbà mẹ́ta.” Ó sì rẹ̀ ẹ́ láti inú ọkàn wá, ó sì sọkún.

  15. Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrín àgbàlá, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Peteru jókòó láàrín wọn.

  16. Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”

  17. Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.”

  18. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.” Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kọ́.”

  19. Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Galili ní í ṣe.”

  20. Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ!

  21. Olúwa sì yípadà, ó wo Peteru. Peteru sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.”

  22. Peteru sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.

  23. Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà wí fún Peteru pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí?” Ó wí pé, “Èmi kọ́.”

  24. Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn aláṣẹ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí ti òtútù mú, wọ́n sì ń yáná, Peteru sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná.

  25. Ṣùgbọ́n Simoni Peteru dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?” Ó sì sẹ́, wí pé, “Èmi kọ́.”