Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Peter: Visits the sepulcher
Àwọn ẹsẹ nípa Visits the sepulcher
Nígbà náà ni Peteru dìde, ó súré lọ sí ibojì; nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnra wọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe.
Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Simoni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn wá, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”
Nígbà náà ni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà jáde, wọ́n sì wá sí ibojì.
Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn náà sì sáré ya Peteru, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì.
Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀.
Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀.