Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Obedience

136 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.

  2. Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè, nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.

  3. Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé, ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.

  4. Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó! Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.

  5. Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ, nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.

  6. Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.

  7. Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ ni ó kọ́ mi.

  8. Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ; nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.

  9. Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi.

  10. Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ.

  11. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi nígbà gbogbo, èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.

  12. Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́ láé dé òpin.

  13. Òfin rẹ̀ ìyanu ni: nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.

  14. Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, Olúwa, èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.

  15. Èmi gba òfin rẹ gbọ́, nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀.

  16. Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ, nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.

  17. Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.

  18. ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”

  19. Ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.

  20. Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ẹ́ jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójútì baba rẹ̀.

  21. Tí ẹ̀yin bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́rọ̀, ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà.

  22. Mo pàṣẹ fún wọn báyìí pé; gbọ́ tèmi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. Máa rìn ní ojú ọ̀nà tí mo pàṣẹ fún yín, kí ó lè dára fún yín.

  23. “Síbẹ̀, ẹ tún ń béèrè pé, ‘Kí ló dé ti ọmọ kò fi ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀?’ Níwọ́n ìgbà tí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ, tó sì ti kíyèsi ara láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, nítòótọ́ ni pé yóò yè.

  24. Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, ‘Ìwọ yóò kú dandan,’ ṣùgbọ́n tí ó bá yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ti o sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí o yẹ.

  25. Tí ó bá mu ògo padà, tí o sì da ohun tí o ti jí gbé padà, tí ó sì tẹ̀lé òfin tí ó ń fún ni ní ìyè, tí kò sì ṣe búburú, òun yóò yè dandan; òun kì yóò kú.