Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Obedience

136 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. A kò ní rántí ọ̀kan nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá. Ó ti ṣe èyí tí ó tọ àti èyí tí o yẹ; òun yóò sì yè dájúdájú.

  2. Lóòótọ́, Daniẹli mọ̀ pé a ti fi ọwọ́ sí ìwé òfin náà, síbẹ̀ ó wọ ilé e rẹ̀ lọ, nínú yàrá òkè, ó ṣí fèrèsé èyí tí ó kọjú sí Jerusalẹmu sílẹ̀. Ó kúnlẹ̀ lórí orúnkún un rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lójoojúmọ́, ó gbàdúrà, ó fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

  3. Nígbà náà, ni a ó gba ìjọba, agbára àti títóbi ìjọba rẹ̀ ní abẹ́ gbogbo ọ̀run, a ó sì fi fún àwọn ẹni mímọ́, àwọn ènìyàn Ọ̀gá-ògo. Ìjọba rẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba títí ayé, gbogbo aláṣẹ ni yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí i, wọn yóò sì máa sìn ín.’

  4. Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jùlọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jùlọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe wọ́n, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run.

  5. “Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.

  6. Bí Jesu sì ti ń rékọjá láti ibẹ̀ lọ, o rí ọkùnrin kan ti à ń pè ní Matiu, ó jókòó ní ibùdó àwọn agbowó òde, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn,” Matiu sì dìde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

  7. Nítorí náà, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”

  8. Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́rùn-ún, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ti ó gbìn.

  9. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba irúgbìn tí ó bọ́ sí orí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì yé e; òun sì so èso òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rùn, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n.”

  10. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún, mú márùn-ún mìíràn padà wá, ó wí pé, ‘Olúwa, ìwọ ti fi tálẹ́ǹtì márùn-ún fún mi, mo sì ti jèrè márùn-ún mìíràn pẹ̀lú rẹ̀.’

  11. “Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́: ìwọ ṣe olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’

  12. “Èyí tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì wí pé ‘Olúwa, ìwọ fún mi ní tálẹ́ǹtì méjì láti lò, èmi sì ti jèrè tálẹ́ǹtì méjì mìíràn.’

  13. “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́. Ìwọ ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ ṣe olórí ohun púpọ̀. Ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’

  14. Bí ó ti ń rin etí Òkun lọ sókè, ó rí Lefi ọmọ Alfeu tí ó jókòó nínú àgọ́ níbi tí ó ti ń gba owó orí, Jesu sì wí fún un pé, “Tẹ̀lé mi,” Lefi dìde, ó sì ń tẹ̀lé e.

  15. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, òun ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”

  16. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà á lóòtítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.”

  17. Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn.

  18. “Nítorí náà, èéṣe tí ẹ̀yin ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ tí ẹ̀yin kò sì ṣe ohun tí mo wí?

  19. Ẹnikẹ́ni tí ó tọ̀ mí wá, tí ó sì ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì ń ṣe é, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín.

  20. Ó jọ ọkùnrin kan, tí ó kọ́ ilé, tí ó sì wa ilẹ̀ jìn, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta, nígbà tí kíkún omi sì dé, ìgbì omi kọlu ilé náà, kò sì lè mì ín nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta.

  21. Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dìímú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso.

  22. Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn wọ̀nyí tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe é.”

  23. Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ máa wí pé: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ yín. Kí ìjọba yín dé, ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe, bí i ti ọrun, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.

  24. Ṣùgbọ́n òun wí pé, nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́!”

  25. Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà nígbà tí olúwa náà bá dé tí yóò bá wọn tí wọn ń ṣọ́nà; lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò di ara rẹ̀ ní àmùrè yóò sì mú wọn jókòó láti jẹun, yóò sì jáde wá láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.