Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Malice

135 ẹsẹ · 29 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀; kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.

  2. Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.

  3. “Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa; jẹ́ kí Olúwa gbà á là. Jẹ́ kí ó gbà á là, nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”

  4. Wọ́n fi búburú san ìre fún mi; láti sọ ọkàn mi di òfo.

  5. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀; mo fi àwẹ̀ pọ́n ara mi lójú. Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi;

  6. èmí ń lọ kiri bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀ bí i ẹni wí pé fún ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ni. Èmí tẹríba nínú ìbànújẹ́ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyà rẹ̀.

  7. Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì kó ara wọn jọ; wọ́n kó ara wọn jọ sí mi; àní àwọn tí èmi kò mọ̀. Wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́.

  8. Bí àwọn àgàbàgebè tí ń ṣe ẹlẹ́yà ní àpèjẹ wọ́n pa eyín wọn keke sí mi.

  9. Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ lórí ì mi; bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe àwọn tí ó kórìíra mi ní àìnídìí máa ṣẹ́jú sí mi.

  10. Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà, ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà.

  11. Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi; wọ́n wí pé, “Háà! Háà! Ojú wa sì ti rí i.”

  12. Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé, “Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”

  13. Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí, wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀; nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.

  14. Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi; èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,

  15. wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí, kì yóò dìde mọ́.”

  16. Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri; ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.

  17. Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀; ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.

  18. Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́, wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.

  19. Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba. Wọ́n ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.

  20. Wò ó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí! Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi kì í ṣe nítorí ìrékọjá mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, Olúwa.

  21. Èmi kò ṣe àìṣedéédéé kan, síbẹ̀ wọ́n sáré wọ́n ṣetán láti kọlù mí. Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi.

  22. Wọ́n padà ní àṣálẹ́, wọ́n ń gbó bí àwọn ajá, wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.

  23. Kíyèsi ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu: wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn, wọ́n sì wí pé, “Ta ni ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?”

  24. Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó? Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á, bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?

  25. Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú kúrò nínú ọlá rẹ̀; inú wọn dùn sí irọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. Sela.