Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Malice: General references

111 ẹsẹ · 29 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.

  2. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ. Èmi ni Olúwa.

  3. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládùúgbò o rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  4. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣi afọ́jú lọ́nà ní ojú ọ̀nà.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  5. Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sodomu àti ti ìgbẹ́ ẹ Gomorra. Èso àjàrà wọn kún fún oró, ìdì wọn korò.

  6. Ọtí wáìnì wọn ìwọ ti dragoni ni, àti oró mímú ti ejò paramọ́lẹ̀.

  7. Nígbà tí ọba Israẹli rí wọn, ó béèrè lọ́wọ́ Eliṣa pé, “Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n, baba mi? Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n?”

  8. “Má ṣe pa wọ́n,” ó dáhùn. “Ṣé ìwọ yóò pa àwọn ọkùnrin tí ìwọ mú pẹ̀lú idà rẹ tàbí ọrun rẹ? Gbé oúnjẹ àti omi síwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ kí wọn sì mu, nígbà náà kí wọn padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn.”

  9. “Bí ó bá ṣe pé mo yọ̀ sì ìparun ẹni tí ó kórìíra mi. Tàbí bí mo bá sì gbéraga sókè, nígbà tí ibi bá a.

  10. Bẹ́ẹ̀ èmi kò sì jẹ ki ẹnu mi ki ó ṣẹ̀ nípa fífẹ́ ègún sí ọkàn rẹ̀.

  11. Ẹni tí ó lóyún ohun búburú, tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde.

  12. Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.

  13. Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀; ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀.

  14. Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ; wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.

  15. Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò. Ò gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀. Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.

  16. Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí; Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́; ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.

  17. Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀; kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.

  18. Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.

  19. “Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa; jẹ́ kí Olúwa gbà á là. Jẹ́ kí ó gbà á là, nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”

  20. Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì kó ara wọn jọ; wọ́n kó ara wọn jọ sí mi; àní àwọn tí èmi kò mọ̀. Wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́.

  21. Bí àwọn àgàbàgebè tí ń ṣe ẹlẹ́yà ní àpèjẹ wọ́n pa eyín wọn keke sí mi.

  22. Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ lórí ì mi; bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe àwọn tí ó kórìíra mi ní àìnídìí máa ṣẹ́jú sí mi.

  23. Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà, ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà.

  24. Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi; wọ́n wí pé, “Háà! Háà! Ojú wa sì ti rí i.”

  25. Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé, “Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”