Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Earth

58 ẹsẹ · 11 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ láti kó àwọn àyànfẹ́ ní gbogbo ayé jọ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé láti ìkangun ayé títí dé ìkangun ọ̀run.

  2. “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́, nígbà tí ẹ̀ka rẹ bá ń yọ tuntun, tí ó bá sì ń rú ewé, èyí fihàn pé àkókò ẹ̀rùn ti dé.

  3. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ ba ri àwọn ohun wọ̀nyí ti n ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó súnmọ́ etílé tán, bi ìgbà tí ó wà lẹ́yìn ìlẹ̀kùn.

  4. Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ìran yìí kì yóò rékọjá títí a ó fi mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹ.

  5. Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi dúró dájú títí ayé àìnípẹ̀kun.

  6. “Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀. Àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀. Àní, èmi pẹ̀lú kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe baba nìkan.

  7. Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró wámú, kí ẹ sì máa gbàdúrà, nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà tí àkókò ná yóò dé.

  8. Ó dà bí ọkùnrin kan tí ó lọ sí ìrìnàjò tí ó jìnnà rere, ẹni tí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì fi àṣẹ fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti iṣẹ́ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò ṣe, ó sì fi àṣẹ fún ẹni tó dúró lẹ́nu-ọ̀nà láti máa ṣọ́nà.

  9. “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin pẹ̀lú ní láti máa fi ìrètí ṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ àkókò tí baálé ilé yóò dé. Bóyá ní ìrọ̀lẹ́ ni o, tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru, tàbí nígbà tí àkùkọ máa ń kọ, tàbí ní òwúrọ̀.

  10. Àti wí pé nígbà tí ó bá dé lójijì, kó má ṣe bá yín lójú oorun.

  11. Ohun tí mo wí fún un yín, mo wí fun gbogbo ènìyàn: ‘Ẹ máa ṣọ́nà!’ ”

  12. Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì.

  13. Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.

  14. Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”

  15. Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ẹ kíyèsi igi ọ̀pọ̀tọ́, àti sí gbogbo igi.

  16. Nígbà tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin rí i, ẹ sì mọ̀ fúnra ara yín pé, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kù fẹ́ẹ́rẹ́.

  17. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, nígbà tí ẹ̀yin bá rí nǹkan wọ̀nyí tí o ṣẹ, kí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.

  18. “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò rékọjá, títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ.

  19. Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.

  20. “Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn.

  21. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé.

  22. Ǹjẹ́ kì ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ ba à lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.”

  23. Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run.

  24. Nítorí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í ṣe bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí.

  25. Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkára rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdíbàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run.