Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Earth

58 ẹsẹ · 11 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí òfúrufú kí ó wà ní àárín àwọn omi, láti pààlà sí àárín àwọn omi.”

  2. Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

  3. Ọlọ́run sì wí fún Adamu pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’ “Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ; nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

  4. Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èṣùṣú fún ọ, ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ.

  5. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

  6. Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà; gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ. Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn wọn yóò sì di àpatì.

  7. Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀, ọdún rẹ kò sì ní òpin.

  8. O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀; tí a kò le è mì láéláé.

  9. Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ; àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.

  10. Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ, nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ.

  11. wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀, sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.

  12. Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀; láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.

  13. Ilẹ̀ ayé ti fọ́ ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù, a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.

  14. Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí, ó bì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́; ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rù tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.

  15. “Lójúkan náà, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, “ ‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn; àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀, agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’

  16. “Nígbà náà ni àmì Ọmọ Ènìyàn yóò sì fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá.

  17. Yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú ohùn ìpè ńlá, wọn yóò sì kó gbogbo àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé àti ọ̀run jọ.

  18. Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.

  19. “Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan ti ó mọ ọjọ́ àti wákàtí tí òpin náà yóò dé, àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀ ọ́n. Àní, ọmọ kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba mi nìkan ṣoṣo ló mọ̀ ọ́n.

  20. Bí ó ṣe rí ní ìgbà ayé Noa, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò sì rí.

  21. Nítorí bí àwọn ọjọ́ náà ti wà ṣáájú ìkún omi, tí wọ́n ń jẹ́ tí wọ́n ń mu, tí wọ́n ń gbéyàwó, tí wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí tí ó fi di ọjọ́ tí Noa fi bọ́ sínú ọkọ̀.

  22. Ènìyàn kò gbàgbọ́ nípa ohun tí o ṣẹlẹ̀ títí tí ìkún omi fi dé nítòótọ́, tí ó sì kó wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn.

  23. “Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ wọ̀nyí lẹ́yìn ìpọ́njú tí mo sọ yìí, “ ‘oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

  24. Àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú yóò já lulẹ̀ láti ojú ọ̀run, àti agbára tí ń bẹ ní ọ̀run ni a ó sì mì tìtì.’

  25. “Nígbà náà ni gbogbo ayé yóò sì rí i tí èmi Ọmọ Ènìyàn yóò máa bọ̀ wá láti inú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.