- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Earth
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá ni ó jùmọ̀ ń kérora tí ó sì ń rọbí pọ̀ títí di ìsinsin yìí.
Ó tún sọ pé, “Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀, àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ.
Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀ gbogbo wọn ni yóò di àkísà bí ẹ̀wù.
Ní kíká ni ìwọ yóò ká wọn bí aṣọ, bí ìpààrọ̀ aṣọ ni a ó sì pààrọ̀ wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ fúnra rẹ̀ kì yóò yípadà àti pé ọdún rẹ kì yóò ní òpin.”
Ṣùgbọ́n ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá bí olè ní òru; nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá, àti àwọn ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́, ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ó wà nínú rẹ̀ yóò sì jóná túútúú.
Ǹjẹ́ bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti yọ́ bẹ́ẹ̀, irú ènìyàn wo ni ẹ̀yin ìbá jẹ́ nínú ìwà mímọ́ gbogbo àti ìwà-bí-Ọlọ́run.
Kí ẹ máa retí, kí ẹ sì máa múra gírí de dídé ọjọ́ Ọlọ́run, nítorí èyí tí àwọn ọ̀run yóò gbiná, tí wọn yóò di yíyọ́, tí àwọn ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́.
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, àwa ń retí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé títún nínú èyí tí òdodo ń gbé.