Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Abraham

314 ẹsẹ · 39 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Isaaki sì sọ fún Abrahamu baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.” Abrahamu sì dalóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi.” Isaaki sì tún wí pé, “Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà?”

  2. Abrahamu sì dáhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì jùmọ̀ ń lọ.

  3. Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Abrahamu, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igi lé e lórí, ó sì di Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà.

  4. Abrahamu sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀.

  5. Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa ké sí i láti ọ̀run wá wí pé “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

  6. Angẹli Olúwa sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí.”

  7. Abrahamu sì gbójú sókè, ó sì rí àgbò kan tí ó fi ìwo há pàǹtírí, ó sì lọ mú un, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀.

  8. Abrahamu sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, Jehofah Jire. Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè Olúwa, ni a ó ti pèsè.”

  9. Angẹli Olúwa sì tún pe Abrahamu láti ọ̀run wá lẹ́ẹ̀kejì.

  10. Ó sì wí pé, Olúwa wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí,

  11. nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn,

  12. àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu.”

  13. Nígbà náà ni Abrahamu padà tọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn sì padà lọ sí Beerṣeba. Abrahamu sì jókòó ní Beerṣeba.

  14. Sara sì pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínláàádóje (127).

  15. Ó sì kú ní Kiriati-Arba (ìyẹn ní Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti sọkún nítorí Sara.

  16. Abrahamu sì dìde lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú aya rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ará Hiti wí pé,

  17. “Èmi jẹ́ àtìpó àti àlejò láàrín yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí.”

  18. Àwọn ọmọ Hiti dá Abrahamu lóhùn pé,

  19. “Olúwa mi, gbọ́ tiwa, ó jẹ́ alágbára ọmọ-aládé láàrín wa, sin òkú rẹ sí ibojì tí ó dára jù nínú àwọn ibojì wa, kò sí ẹni tí yóò fi ibojì rẹ dù ọ́ láti sin òkú rẹ sí.”

  20. Nígbà náà ni Abrahamu dìde, ó sì tẹríba níwájú àwọn ará ilẹ̀ náà, àwọn ará Hiti.

  21. Ó sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá ṣe pé, lóòótọ́ ni ẹ fẹ́ kí n sin òkú mi kúrò nílẹ̀, ẹ gbọ́ tèmi, ẹ bá mi bẹ Efroni ọmọ Sohari,

  22. kí ó ta ihò àpáta Makpela tí ó jẹ́ tirẹ̀ fún mi, èyí tí ó wà ni orí oko rẹ̀, kí ó tà á fún mi ni iye owó tí à ń ta irú rẹ̀ fún ilẹ̀ ìsìnkú láàrín yín.”

  23. Efroni ará Hiti sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú, ó sì dá Abrahamu lóhùn lójú gbogbo àwọn ará ìlú tí ó wà níbẹ̀, lẹ́nu ibodè ìlú,

  24. pé, “Rárá, olúwa mi. Gbọ́ tèmi; mo fún ọ ní ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà níbẹ̀. Mo fún ọ níwájú gbogbo àwọn ènìyàn mi. Sin òkú rẹ síbẹ̀.”

  25. Abrahamu sì tún tẹríba níwájú àwọn ènìyàn ìlú náà,