- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446–1406 BC
The Wilderness Years
Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Deuteronomi 5:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Olúwa Ọlọ́run wa bá wa dá májẹ̀mú ní Horebu.
- Deuteronomi 5:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Kì í ṣe àwọn baba wa ni Olúwa bá dá májẹ̀mú yìí bí kò ṣe àwa, àní pẹ̀lú gbogbo àwa tí a wà láààyè níbí lónìí.
- Deuteronomi 5:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Olúwa bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú láàrín iná lórí òkè.
- Deuteronomi 5:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
(Ní ìgbà yìí, mo wà láàrín ẹ̀yin pẹ̀lú Ọlọ́run láti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un yín torí pé ẹ̀rù Ọlọ́run ń bà yín, ẹ kò sì lè kọjá lọ sórí òkè.) Ó sì wí pé,
- Deuteronomi 5:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá.
- Deuteronomi 5:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.
- Deuteronomi 5:8nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀.
- Deuteronomi 5:9nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi.
- Deuteronomi 5:10nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.
- Deuteronomi 5:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹ má ṣe ṣi orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi.
- Deuteronomi 5:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́, bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín.
- Deuteronomi 5:13nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ.
- Deuteronomi 5:14nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti akọ màlúù rẹ, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, àti ohun ọ̀sìn rẹ kan, àti àlejò tí ń bẹ nínú ibodè rẹ; kí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin kí ó lè sinmi gẹ́gẹ́ bí ìwọ.
- Deuteronomi 5:15nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Sì rántí pé, ìwọ ti jẹ́ ẹrú ní Ejibiti rí, àti pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yọ ọ́ kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá, àti nína ọwọ́ rẹ̀. Torí èyí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ ṣe pàṣẹ fún ọ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́.
- Deuteronomi 5:16nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún ọ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́, àti kí ó lè dára fún ọ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.
- Deuteronomi 5:17nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.
- Deuteronomi 5:18nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.
- Deuteronomi 5:19nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.
- Deuteronomi 5:20nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.
- Deuteronomi 5:21nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéji rẹ, oko rẹ̀, àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéji rẹ.”
- Deuteronomi 5:22nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ Olúwa tí a kéde rẹ̀ sí gbogbo ìpéjọpọ̀ ọ yín, níbẹ̀ ní orí òkè, láàrín iná, ìkùùkuu àti òkùnkùn biribiri, kò sì fi ohunkóhun kún un mọ́. Ó sì kọ wọ́n sínú wàláà méjì, Ó sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́.
- Deuteronomi 5:23nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ẹ gbóhùn láti inú òkùnkùn wá, nígbà tí iná náà ń yọ iná lala, àwọn aṣáájú ẹ̀yà a yín àti àwọn àgbàgbà yín tọ̀ mí wá.
- Deuteronomi 5:24nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹ sì sọ pé, “Olúwa Ọlọ́run wa ti fi ògo rẹ̀ hàn wá, àti títóbi rẹ̀ a sì ti gbóhùn rẹ̀ láti àárín iná wá. A ti rí i lónìí pé, ènìyàn sì lè wà láààyè lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá bá a sọ̀rọ̀.
- Deuteronomi 5:25nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n èéṣe tí àwa yóò fi kú? Iná ńlá yìí yóò jó wa run, bí àwa bá sì tún gbọ́ ohun Olúwa Ọlọ́run wa, àwa ó kú.
- Deuteronomi 5:26nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ta ni nínú ẹlẹ́ran ara tí ó ti gbọ́ ohun Ọlọ́run alààyè láti inú iná rí, bí àwa ti gbọ́ ọ, tí a sì wà láyé?