Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Deuteronomi 4:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Gbọ́ Israẹli, gbọ́ òfin àti ìlànà tí èmi yóò kọ́ ọ yín. Ẹ tẹ̀lé wọn kí ẹ ba à lè yè, kí ẹ ba à lè lọ láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín yóò fi fún un yín.

  2. Deuteronomi 4:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ẹ má ṣe fi kún àwọn ohun tí mo pàṣẹ fún un yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ yọ kúrò nínú wọn, ṣùgbọ́n ẹ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín tí mo fún un yín mọ́.

  3. Deuteronomi 4:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí Olúwa ṣe ní Baali-Peori. Olúwa Ọlọ́run yín run gbogbo àwọn tí ó tẹ̀lé òrìṣà Baali-Peori kúrò ní àárín yín.

  4. Deuteronomi 4:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ ni ẹ wà láààyè lónìí.

  5. Deuteronomi 4:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ẹ kíyèsi i, mo ti kọ́ ọ yín ní àwọn òfin àti àṣẹ bí Olúwa Ọlọ́run mi ti pàṣẹ fún mi, kí ẹ ba à le tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń lọ láti ní ní ìní.

  6. Deuteronomi 4:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ẹ máa kíyèsi wọn dáradára. Èyí ni yóò fi ọgbọ́n àti òye yín han àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn tí wọn yóò gbọ́ nípa àwọn ìlànà wọ̀nyí, tí wọn yóò sì máa wí pé, “Dájúdájú, orílẹ̀-èdè ńlá yìí kún fún ọgbọ́n àti òye.”

  7. Deuteronomi 4:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Orílẹ̀-èdè olókìkí wo ni ọlọ́run wọn tún súnmọ́ wọn, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti súnmọ́ wa nígbàkígbà tí a bá ń ké pè é?

  8. Deuteronomi 4:8nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Orílẹ̀-èdè wo ló tún le lókìkí láti ní àwọn ìlànà òdodo, àti òfin gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin wọ̀nyí tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.

  9. Deuteronomi 4:9nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì ṣọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láààyè. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn.

  10. Deuteronomi 4:10nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ẹ rántí ọjọ́ tí ẹ dúró níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní Horebu, nígbà tí ó wí fún mi pé, “Kó àwọn ènìyàn wọ̀nyí jọ síwájú mi láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bu ọlá náà fún mi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé lórí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì le è fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn.”

  11. Deuteronomi 4:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀yin súnmọ́ tòsí, ẹ sì dúró ní ẹsẹ̀ òkè náà, òkè náà sì ń jóná dé agbede-méjì ọrun, pẹ̀lú òkùnkùn, àti àwọsánmọ̀, àti òkùnkùn biribiri.

  12. Deuteronomi 4:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì bá yín sọ̀rọ̀ láti àárín iná náà wá. Ẹ gbọ́ àwọn ìró ohùn, ṣùgbọ́n ẹ kò rí ẹnikẹ́ni, ohùn nìkan ni ẹ gbọ́.

  13. Deuteronomi 4:13nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ó sọ àwọn májẹ̀mú rẹ̀ fún un yín àní àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó pàṣẹ fún un yín láti máa tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sórí wàláà òkúta méjì.

  14. Deuteronomi 4:14nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì pàṣẹ fún mi nígbà náà láti kọ yín ní ìlànà àti ìdájọ, kí ẹ̀yin kí ó lè máa ṣe wọ́n ní ilẹ̀ náà, ní ibi tí ẹ̀yin ń lọ láti gbà á.

  15. Deuteronomi 4:15nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ẹ kíyèsára gidigidi, torí pé, ẹ kò rí ìrísí ohunkóhun ní ọjọ́ tí Olúwa bá yín sọ̀rọ̀ ní Horebu láti àárín iná wá. Torí náà ẹ ṣọ́ra yín gidigidi,

  16. Deuteronomi 4:16nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    kí ẹ ma ba à ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe ère fún ara yín, àní ère lóríṣìíríṣìí yálà èyí tí ó ní ìrísí ọkùnrin tàbí tí obìnrin,

  17. Deuteronomi 4:17nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    tàbí ti ẹranko orí ilẹ̀, tàbí ti ẹyẹ tí ń fò ní òfúrufú,

  18. Deuteronomi 4:18nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    tàbí ti àwòrán onírúurú ẹ̀dá tí ń fà lórí ilẹ̀, tàbí ti ẹja nínú omi.

  19. Deuteronomi 4:19nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí ẹ bá wòkè tí ẹ rí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀: àwọn ohun tí a ṣe lọ́jọ̀ sójú ọ̀run, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ dé bi pé ẹ̀yin yóò foríbalẹ̀ fún wọn, àti láti máa sin ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín dá fún gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run.

  20. Deuteronomi 4:20nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Olúwa Ọlọ́run yín sì ti mú ẹ̀yin jáde kúrò nínú iná ìléru ńlá, àní ní Ejibiti, láti lè jẹ́ ènìyàn ìní i rẹ̀, bí ẹ̀yin ti jẹ́ báyìí.

  21. Deuteronomi 4:21nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Inú Olúwa ru sí mi nítorí yín, ó sì ti búra pé èmi kì yóò la Jordani kọjá, èmi kì yóò sì wọ ilẹ̀ rere tí Olúwa Ọlọ́run fi fún un yín, ní ìní yín.

  22. Deuteronomi 4:22nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò kú ní ilẹ̀ yìí, èmi kì yóò la Jordani kọjá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti fẹ́ rékọjá sí òdìkejì odò láti gba ilẹ̀ rere náà.

  23. Deuteronomi 4:23nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti bá a yín dá. Ẹ má ṣe ṣe ère ní ìrísí ohunkóhun fún ara yín, èèwọ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín kà á sí.

  24. Deuteronomi 4:24nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Torí pé iná ajónirun ni Olúwa Ọlọ́run yín, Ọlọ́run owú ni.

  25. Deuteronomi 4:25nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti ní àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ sì ti gbé ní ilẹ̀ yìí pẹ́, bí ẹ bá wá ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe irú ère yówù tó jẹ́, tí ẹ sì ṣe búburú lójú Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì mú un bínú.