Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Deuteronomi 6:19nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀yin yóò sì ti àwọn ọ̀tá yín jáde níwájú u yín bí Olúwa ti ṣèlérí.

  2. Deuteronomi 6:20nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ iwájú, bí ọmọ rẹ bá béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin wọ̀nyí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún ọ?”

  3. Deuteronomi 6:21nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Sọ fún un pé: “Ẹrú Farao ní ilẹ̀ Ejibiti ni wá tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa fi ọwọ́ agbára ńlá yọ wá jáde lóko ẹrú Ejibiti.

  4. Deuteronomi 6:22nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Lójú wa ni Olúwa tí ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu: tí ó lágbára tí ó sì ba ni lẹ́rù: lórí Ejibiti àti Farao, àti gbogbo ènìyàn rẹ̀.

  5. Deuteronomi 6:23nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ó mú wa jáde láti ibẹ̀ wá láti mú wa wọ inú àti láti fún wa ní ilẹ̀ tí ó ti fì búra fún àwọn baba ńlá wa.

  6. Deuteronomi 6:24nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Olúwa pàṣẹ fún wa láti ṣe ìgbọ́ràn sí gbogbo ìlànà wọ̀nyí, láti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, kí ó ba à lè máa dára fún wa nígbà gbogbo, kí a sì lè wà láyé, bí a ṣe wà títí di òní.

  7. Deuteronomi 6:25nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí a bá ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin wọ̀nyí mọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, bí ó ti pàṣẹ fún wa, èyí ni yóò máa jẹ́ òdodo wa.”

  8. Deuteronomi 7:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ náà, tí ìwọ yóò wọ̀ lọ láti gbà, tí ìwọ yóò sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè kúrò níwájú rẹ. Àwọn ará Hiti, Girgaṣi, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi. Àwọn orílẹ̀-èdè méje tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì pọ̀jù ọ lọ,

  9. Deuteronomi 7:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì ti fi wọ́n lé ẹ lọ́wọ́, tí ìwọ sì ti ṣẹ́gun wọn, kí ìwọ kí ó sì pa wọ́n run pátápátá. Má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú fún wọn.

  10. Deuteronomi 7:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ bá wọn dá àna. Àwọn ọmọbìnrin rẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọkùnrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ,

  11. Deuteronomi 7:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    torí pé wọ́n yóò yí àwọn ọmọ rẹ padà kúrò lẹ́yìn mi, láti jẹ́ kí wọn máa sin òrìṣà, ìbínú Olúwa yóò sì wá sórí rẹ, yóò sì run yín kíákíá.

  12. Deuteronomi 7:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Èyí ni kí ẹ ṣe sí wọn, ẹ wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ bi òpó òkúta ibi mímọ́ òrìṣà wọn lulẹ̀, òpó òrìṣà Aṣerah wọn ni kí ẹ gé lulẹ̀ kí ẹ sì sun ère òrìṣà wọn ní iná.

  13. Deuteronomi 7:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Torí pé ènìyàn mímọ́ ni ẹ jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run yín, Olúwa Ọlọ́run yín ti yàn yín láàrín gbogbo ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀: ohun ìní iyebíye rẹ̀.

  14. Deuteronomi 7:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Olúwa kò torí pé ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ju àwọn ènìyàn yòókù lọ yàn yín, ẹ̀yin sá à lẹ kéré jù nínú gbogbo ènìyàn.

  15. Deuteronomi 7:8nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n torí Olúwa fẹ́ràn yín, tí ó sì pa ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín mọ́ ni ó ṣe fi ọwọ́ agbára ńlá mú un yín jáde tí ó sì rà yín padà nínú oko ẹrú, àti láti ọwọ́ agbára Farao ọba Ejibiti.

  16. Deuteronomi 7:9nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé Olúwa Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olóòtítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.

  17. Deuteronomi 7:10nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ni yóò san ẹ̀san fún ní gbangba nípa pípa wọ́n run; kì yóò sì jáfara láti san ẹ̀san fún àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ní gbangba.

  18. Deuteronomi 7:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa tẹ̀lé àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí mo fun un yín lónìí.

  19. Deuteronomi 7:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí ẹ bá ń kíyèsi àwọn òfin wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣọ́ra láti ṣe wọ́n, nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún un yín, bí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín.

  20. Deuteronomi 7:13nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Yóò fẹ́ràn yín, yóò bùkún un yín yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i. Yóò bùkún èso inú yín, ọ̀gbìn ilẹ̀ yín, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun àti òróró yín, àwọn màlúù, agbo ẹran yín, àti àwọn àgùntàn, ọ̀wọ́ ẹran yín, ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá yín láti fún un yín.

  21. Deuteronomi 7:14nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    A ó bùkún un yín ju gbogbo ènìyàn lọ, kò sí ẹni tí yóò yàgàn nínú ọkùnrin tàbí obìnrin yín, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀kan nínú àwọn ohun ọ̀sìn in yín tí yóò wà láìlọ́mọ.

  22. Deuteronomi 7:15nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ààrùn gbogbo, kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí ààrùn búburú tí ẹ mọ̀ ní Ejibiti wá sára yín, ṣùgbọ́n yóò fi wọ́n lé ara gbogbo àwọn tí ó kórìíra yín.

  23. Deuteronomi 7:16nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn ènìyàn tí Olúwa Ọlọ́run yín fi lé yín lọ́wọ́ ni kí ẹ parun pátápátá. Ẹ má ṣe ṣàánú fún wọn, ẹ má ṣe sin olúwa ọlọ́run wọn torí pé ìdánwò ni èyí jẹ́ fún un yín.

  24. Deuteronomi 7:17nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ẹ lè máa rò láàrín ara yín pé, “Àwọn orílẹ̀-èdè yìí lágbára jù wá lọ. Báwo ni a o ṣe lé wọn jáde?”

  25. Deuteronomi 7:18nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, ẹ rántí dáradára ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe sí Farao àti gbogbo Ejibiti.