circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Marku 13:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bí Jesu si ti jókòó lórí òkè olifi tí ó kọjú sí tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkọ̀kọ̀ pé,
- Marku 13:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Sọ fún wa, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ sí tẹmpili náà? Kí ni yóò sì jẹ́ àmì nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ?”
- Marku 13:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín.
- Marku 13:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, wọn yóò wí pé, ‘Èmi ni Kristi,’ wọn yóò tan ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ.
- Marku 13:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà, nítorí irú nǹkan wọ̀nyí kò le ṣe kí ó má ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe ìgbà yìí.
- Marku 13:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba ilẹ̀ yóò máa jì ní ibi púpọ̀. Ìyàn yóò sì wà níbi gbogbo. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ń bọ̀ níwájú.
- Marku 13:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyèsára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu. Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo. Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú Sinagọgu wọn. Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn baálẹ̀ àti níwájú àwọn ọba nítorí orúkọ mi, fún ẹ̀rí fún wọn.
- Marku 13:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìyìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin tó dé.
- Marku 13:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń fà yín lọ, tí wọ́n bá sì ń fi yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣe ṣàníyàn ṣáájú ohun tí ẹ ó sọ. Ṣùgbọ́n ohun tí bá fi fún yín ní wákàtí náà, òun ni kí ẹ̀yin kí ó wí. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń wí, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́.
- Marku 13:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣe ikú pa òbí wọn.
- Marku 13:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ènìyàn yóò kórìíra yín nítorí tí ẹ jẹ́ tèmi. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fi ara da ìyà títí dé òpin tí kò sì kọ̀ mí sílẹ̀ òun ni yóò rí ìgbàlà.
- Marku 13:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí ó dúró níbí tí kò yẹ (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á kí ó yé e), nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè.
- Marku 13:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Kí ẹni ti ń bẹ lórí ilé má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ilé, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe wọ inú rẹ̀, láti mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀.
- Marku 13:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Kí ẹni tí ó wà lóko má ṣe padà sẹ́yìn láti wá mú aṣọ rẹ̀.
- Marku 13:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ègbé ní fún àwọn tí ó lóyún, àti fún obìnrin tí ń fún ọ́mọ lọ́mú ní ọjọ́ wọ̀nyí.
- Marku 13:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Kí ẹ sì máa gbàdúrà pé èyí ṣẹlẹ̀ ní àkókò òtútù.
- Marku 13:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì yóò jẹ́ àkókò ìpọ́njú, irú èyí tí kò ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá Ọlọ́run. Irú rẹ̀ kò sì ni ṣẹlẹ̀ mọ́.
- Marku 13:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Àfi tí Olúwa bá gé àkókò ìjìyà náà kúrú, ẹyọ ẹ̀mí kan ní ayé kì yóò là. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn tí Ọlọ́run yàn, ni yóò ṣe dín àwọn ọjọ́ náà kù.
- Marku 13:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, Kristi wa níbi yìí!’ tàbí, sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn ún nì!’ Ẹ má ṣe gbà wọ́n gbọ́.
- Marku 13:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn. Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ.
- Marku 13:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra. Mo ti kìlọ̀ fún un yín ṣáájú tó!
- Marku 13:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ wọ̀nyí lẹ́yìn ìpọ́njú tí mo sọ yìí, “ ‘oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.
- Marku 13:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú yóò já lulẹ̀ láti ojú ọ̀run, àti agbára tí ń bẹ ní ọ̀run ni a ó sì mì tìtì.’
- Marku 13:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Nígbà náà ni gbogbo ayé yóò sì rí i tí èmi Ọmọ Ènìyàn yóò máa bọ̀ wá láti inú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.
- Marku 13:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ láti kó àwọn àyànfẹ́ ní gbogbo ayé jọ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé láti ìkangun ayé títí dé ìkangun ọ̀run.