Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Marku 14:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì jáde lọ àárín ìlú. Wọ́n bá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jesu tí sọ fún wọn. Wọ́n sì pèsè àsè ìrékọjá.

  2. Marku 14:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó di alẹ́, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé síbẹ̀.

  3. Marku 14:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jesu wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fi mí hàn.”

  4. Marku 14:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú. Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wí pé, “Dájúdájú, kì í ṣe èmi?”

  5. Marku 14:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi tọwọ́ bọ àwo jẹun nísinsin yìí ni.

  6. Marku 14:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítòótọ́ Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n ègbé ní fún ọkùnrin náà, láti ọwọ́ ẹni tí a ti fi Ọmọ Ènìyàn hàn. Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i rárá.”

  7. Marku 14:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí wọ́n ti ń jẹun lọ́wọ́, Jesu mú ìṣù àkàrà kan, ó gbàdúrà sí i. Lẹ́yìn náà ó bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì fi fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ gbà jẹ, èyí yìí ni ara mi.”

  8. Marku 14:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀.

  9. Marku 14:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

  10. Marku 14:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu ọtí wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní tuntun nínú ìjọba Ọlọ́run.”

  11. Marku 14:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn náà wọ́n kọ orin, wọ́n sì gun orí òkè olifi lọ.

  12. Marku 14:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ ó sa kúrò lọ́dọ̀ mi, a ti kọ̀wé rẹ pé, “ ‘Èmi yóò lu olùṣọ́-àgùntàn àwọn agbo àgùntàn yóò sì fọ́nká.’

  13. Marku 14:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà ti mo ba jíǹde tan, èmi yóò síwájú yin lọ sí Galili.”

  14. Marku 14:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn, ó wí pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ sá kúrò lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní sá.”

  15. Marku 14:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu si wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń sọ òótọ́ fún ọ. Kí àkùkọ tó ó kọ lẹ́ẹ̀kejì ní òwúrọ̀ ọ̀la, ìwọ, pàápàá yóò ti sọ lẹ́ẹ̀mẹ́ta wí pe ìwọ kò mọ̀ mí rí.”

  16. Marku 14:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Peteru fa ara ya, ó wí pé, “Bí mo tilẹ̀ ní láti kú pẹ̀lú rẹ̀, èmi kò jẹ́ sọ pé n kò mọ̀ ọ́n rí.” Ìlérí yìí kan náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.

  17. Marku 14:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n dé ibi kan tí wọ́n ń pè ní ọgbà Getsemane. Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó dè mí níhìn-ín títí n ó fi lọ gbàdúrà.”

  18. Marku 14:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì mú Peteru àti Jakọbu àti Johanu lọ pẹ̀lú rẹ̀. Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi.

  19. Marku 14:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wí fún wọn pé, “Ọkàn mi ń káàánú gidigidi títí dé ojú ikú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ sì máa bá mi ṣọ́nà.”

  20. Marku 14:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì lọ síwájú díẹ̀, ó dojúbo ilẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá.

  21. Marku 14:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wí pé, “Ábbà, Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò ṣe èyí tí ìwọ fẹ́.”

  22. Marku 14:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì padà dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun. Ó sì wí fún Peteru pé, “Simoni, o ń sùn ni? Ìwọ kò lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan?

  23. Marku 14:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, ki ẹ má ba à bọ́ sínú ìdánwò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ‘Ẹ̀mí ń fẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.’ ”

  24. Marku 14:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú.

  25. Marku 14:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì tún padà dé, ó bá wọn wọ́n ń sùn, nítorí pé ojú wọn kún fún oorun. Wọn kò sì mọ irú èsì tí wọn ìbá fún un.