circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Marku 12:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àwọn méjèèje sì ṣú u lópó, wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà kú pẹ̀lú.
- Marku 12:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ ní àjíǹde, nígbà tí wọ́n bá jíǹde, aya ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Àwọn méjèèje ni ó sá ni ní aya?”
- Marku 12:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Kì í há ṣe nítorí èyí ni ẹ ṣe ṣìnà, pé ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́, tàbí agbára Ọlọ́run.
- Marku 12:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí pé, nígbà tí àwọn arákùnrin méje yìí àti obìnrin náà bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn. Wọn yóò dàbí àwọn angẹli tí ń bẹ ní ọ̀run.
- Marku 12:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Eksodu, nípa Mose àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.’
- Marku 12:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè: nítorí ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi.”
- Marku 12:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin ti ó dúró níbẹ̀ tí ó sì fetísílẹ̀ dáradára sí àròyé yìí ṣàkíyèsí pé, Jesu ti dáhùn dáradára. Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ?”
- Marku 12:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu dá ọkùnrin yìí lóhùn pé, “Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn òfin ni èyí tí ó kà báyìí pé, ‘Gbọ́ Israẹli; Olúwa Ọlọ́run wa Olúwa kan ni.
- Marku 12:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní.’
- Marku 12:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Èkejì ni pé: ‘Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ.”
- Marku 12:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Olùkọ́ òfin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ nípa pé Ọlọ́run kan ni ó ń bẹ, àti pé kò sí òmíràn àfi òun nìkan.
- Marku 12:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àti kí a fi gbogbo àyà, àti gbogbo òye, àti gbogbo ọkàn àti gbogbo agbára fẹ́ ẹ, àti fẹ́ ọmọnìkejì ẹni bí ara ẹni, ó ju gbogbo ẹbọ sísun, àti ẹbọ lọ.”
- Marku 12:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu rí i dájú pé òye ọkùnrin yìí ga, nítorí náà, Jesu sọ fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ kò jìnà sí à ti dé ìjọba Ọ̀run.” Láti ìgbà náà lọ, ẹnikẹ́ni kò tún béèrè ohun kan lọ́wọ́ Jesu.
- Marku 12:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jesu ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú tẹmpili, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí àwọn olùkọ́ òfin fi gbà wí pé Kristi náà ní láti jẹ́ ọmọ Dafidi?
- Marku 12:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí tí Dafidi tìkára rẹ̀, ti ń ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé: “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’
- Marku 12:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Níwọ́n ìgbà tí Dafidi tìkára rẹ̀ pè é ní ‘Olúwa,’ báwo ni ó túnṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?” Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
- Marku 12:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún wọn nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fun àwọn olùkọ́ òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígùn káàkiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà,
- Marku 12:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu àti ipò ọlá níbi àsè.
- Marku 12:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.”
- Marku 12:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i.
- Marku 12:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀.
- Marku 12:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìí sọ sínú àpótí ìṣúra ju gbogbo àwọn ìyókù to sọ sínú rẹ lọ.
- Marku 12:44nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.”
- Marku 13:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bí Jesu ti ń jáde láti inú tẹmpili ní ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́, wo ilé ńlá tí ó dára wọ̀nyí. Sì wo òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ lára àwọn ògiri ilé náà.”
- Marku 13:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu dáhùn pé, “Ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Kì yóò sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”