Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Marku 11:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, “Ki ni ẹyin n ṣe, tí ẹ̀yin fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ n nì?”

  2. Marku 11:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì wí fún wọn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ní kí wọ́n sọ, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ.

  3. Marku 11:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n fa ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tọ Jesu wá. Wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ẹ̀yìn rẹ̀, òun sì jókòó lórí rẹ̀.

  4. Marku 11:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn púpọ̀ tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà. Àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi, wọ́n sì fọ́n wọn sí ọ̀nà.

  5. Marku 11:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àti àwọn tí ń lọ níwájú, àti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo wọn sì ń kígbe wí pé, “Hosana!” “Olùbùkún ni ẹni náà tí ó ń bọ̀ wà ní orúkọ Olúwa!”

  6. Marku 11:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Olùbùkún ni fún ìjọba tí ń bọ̀ wá, ìjọba Dafidi, baba wa!” “Hosana lókè ọ̀run!”

  7. Marku 11:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu wọ Jerusalẹmu ó sì lọ sí inú tẹmpili. Ó wo ohun gbogbo yíká fínní fínní. Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti ṣú. Ó padà lọ sí Betani pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá.

  8. Marku 11:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Betani, ebi ń pa Jesu.

  9. Marku 11:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán tí ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ láti wò ó bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so.

  10. Marku 11:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn náà, Jesu pàṣẹ fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀.

  11. Marku 11:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà ti wọ́n padà sí Jerusalẹmu, ó wọ inú tẹmpili. Ó bẹ̀rẹ̀ sí nílé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbàárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹmpili ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀.

  12. Marku 11:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Kò sì gba ẹnikẹ́ni láààyè láti gbé ẹrù ọjà títà gba inú tẹmpili wọlé.

  13. Marku 11:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé, “Ṣé a kò ti kọ ọ́ pé: ‘Ilé àdúrà ni a o máa pe ilé mi, ní gbogbo orílẹ̀-èdè?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́ṣà.”

  14. Marku 11:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin gbọ́ ohun tí ó ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbà èrò bí wọn yóò ti ṣe pa á. Wọ́n bẹ̀rù rògbòdìyàn tí yóò bẹ́ sílẹ̀, nítorí tí àwọn ènìyàn ní ìgbóná ọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.

  15. Marku 11:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, bí ìṣe wọn, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú Jerusalẹmu.

  16. Marku 11:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jesu fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò tigbòǹgbò.

  17. Marku 11:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Peteru rántí pé Jesu ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jesu pé, “Rabbi, wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!”

  18. Marku 11:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.

  19. Marku 11:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘Ṣídìí, gbé ara rẹ sọ sínú Òkun,’ ti kò sì ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un.

  20. Marku 11:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ tiyín.

  21. Marku 11:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì, bí ẹ̀yin bá ní ohunkóhun sí ẹnikẹ́ni, kí baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run bá à le dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín.”

  22. Marku 11:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    But if ye do not forgive, neither will your Father which is in heaven forgive your trespasses.

  23. Marku 11:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún padà sí Jerusalẹmu. Bí Jesu ti ń rìn kiri ni tẹmpili, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Júù wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

  24. Marku 11:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Àṣẹ wo ni ó fi ń ṣe nǹkan yìí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí láti máa ṣe nǹkan wọ̀nyí?”

  25. Marku 11:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi yóò bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan, kí ẹ sì dá mi lóhùn, èmi yóò sọ fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”