Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Jeremiah 51:43nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Àwọn ìlú rẹ̀ yóò di ahoro, ilẹ̀ tí ó gbẹ, ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé tí ènìyàn kò sì rin ìrìnàjò.

  2. Jeremiah 51:44nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò fi ìyà jẹ Beli ti Babeli àti pé èmi yóò jẹ́ kí ó pọ gbogbo àwọn ohun tí ó gbé mì. Àwọn orílẹ̀-èdè kì yóò jùmọ̀ sàn lọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́. Ní òótọ́ odi Babeli yóò sì wó.

  3. Jeremiah 51:45nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn mi! Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Sá fún ìbínú ńlá Olúwa.

  4. Jeremiah 51:46nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ dàrú tàbí kí o bẹ̀rù nígbà tí a bá gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ wa; àhesọ ọ̀rọ̀ kan wá ní ọdún yìí, òmíràn ní ọdún mìíràn àhesọ ọ̀rọ̀ ni ti ìwà ipá ní ilẹ̀ náà àti tí aláṣẹ kan sí aláṣẹ kejì.

  5. Jeremiah 51:47nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Nítorí ìgbà náà yóò wá dandan nígbà tí èmi yóò fi ìyà jẹ àwọn òrìṣà Babeli; gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó dójútì gbogbo àwọn tí a pa yóò sì ṣubú ní àárín rẹ̀.

  6. Jeremiah 51:48nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn, yóò sì kọrin lórí Babeli: nítorí àwọn afiniṣèjẹ yóò wá sórí rẹ̀ láti àríwá,” ni Olúwa wí.

  7. Jeremiah 51:49nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    “Babiloni gbọdọ̀ ṣubú nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni Israẹli, gẹ́gẹ́ bí àwọn ti a pa ní gbogbo ayé nítorí Babeli.

  8. Jeremiah 51:50nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀yin tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ lọ, ẹ má dúró. Ẹ rántí Olúwa ní òkèrè, ẹ sì jẹ́ kí Jerusalẹmu wá sí ọkàn yín.”

  9. Jeremiah 51:51nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    “Ojú tì wá, nítorí pé àwa ti gbọ́ ẹ̀gàn: ìtìjú ti bò wá lójú nítorí àwọn àjèjì wá sórí ohun mímọ́ ilé Olúwa.”

  10. Jeremiah 51:52nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    “Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò lórí àwọn ère fínfín rẹ̀, àti àwọn tí ó gbọgbẹ́ yóò sì máa kérora já gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.

  11. Jeremiah 51:53nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Bí Babeli tilẹ̀ gòkè lọ sí ọ̀run, bí ó sì ṣe ìlú olódi ní òkè agbára rẹ, síbẹ̀ àwọn afiniṣèjẹ yóò ti ọ̀dọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá,” ní Olúwa wí.

  12. Jeremiah 51:54nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    “Ìró igbe láti Babeli, àti ìparun láti ilẹ̀ àwọn ará Kaldea!

  13. Jeremiah 51:55nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Nítorí pé Olúwa ti ṣe Babeli ní ìjẹ, ó sì ti pa ohun ńlá run kúrò nínú rẹ̀; àwọn ọ̀tá wọn sì ń hó bi omi púpọ̀, a gbọ́ ariwo ohùn wọn.

  14. Jeremiah 51:56nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Nítorí pé afiniṣèjẹ dé sórí rẹ̀, àní sórí Babeli; a mú àwọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn: nítorí Ọlọ́run ẹ̀san ni Olúwa, yóò san án nítòótọ́.

  15. Jeremiah 51:57nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Èmi ó sì mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ yó bí ọ̀mùtí, àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ àti àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti àwọn akọni rẹ̀, wọn ó sì sun oorun láéláé, wọn kì ó sì jí mọ́,” ní ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  16. Jeremiah 51:58nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Odi Babeli gbígbòòrò ní a ó wó lulẹ̀ pátápátá, ẹnu-bodè gíga rẹ̀ ní a ó sì fi iná sun: tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti ṣiṣẹ́ lásán, àti àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣiṣẹ́ fún iná, tí àárẹ̀ sì mú wọn.”

  17. Jeremiah 51:59nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì pàṣẹ fún Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, nígbà tí o ń lọ ni ti Sedekiah, ọba Juda, sí Babeli ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. Seraiah yìí sì ní ìjòyè ibùdó.

  18. Jeremiah 51:60nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Jeremiah sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ ibi tí yóò wá sórí Babeli sínú ìwé kan, àní gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a kọ sí Babeli.

  19. Jeremiah 51:61nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Jeremiah sì sọ fún Seraiah pé, “Nígbà tí ìwọ bá dé Babeli, kí ìwọ kí ó sì wò, kí ìwọ kí ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.

  20. Jeremiah 51:62nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Kí ìwọ kí ó sì wí pé, ‘Olúwa ìwọ ti sọ̀rọ̀ sí ibí yí, láti ké e kúrò, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀, àti ènìyàn àti ẹran, nítorí pé yóò di ahoro láéláé.’

  21. Jeremiah 51:63nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ bá parí kíka ìwé yìí tán kí ìwọ kí ó di òkúta mọ́ ọn, kí ó sì sọ ọ́ sí àárín odò Eufurate.

  22. Jeremiah 51:64nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Kí ìwọ sì wí pé, ‘Báyìí ní Babeli yóò rì, kí yóò sì tún dìde kúrò nínú ibi tí èmi ó mú wá sórí rẹ̀: àárẹ̀ yóò sì mú wọn.’ ” Títí dé ìhín ni ọ̀rọ̀ Jeremiah.

  23. Jeremiah 52:1nǹkan bí 598 ṣáájú Kristi

    Sedekiah jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó jẹ ọba. Ọdún mọ́kànlá ló fi jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali ọmọ Jeremiah; láti Libina ló ti wá.

  24. Jeremiah 52:2nǹkan bí 598 ṣáájú Kristi

    Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe.

  25. Jeremiah 52:3nǹkan bí 598 ṣáájú Kristi

    Nítorí ìbínú Olúwa ni gbogbo èyí ṣe ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu àti Juda àti ní ìkẹyìn. Ó sì gbà wọ́n gbọ́ ní iwájú rẹ̀. Sedekiah ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli.