circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jeremiah 50:39nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
“Nítorí náà àwọn ẹranko ijù pẹ̀lú ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀, abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀, a kì yóò sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran.
- Jeremiah 50:40nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti gba ìjọba Sodomu àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú agbègbè wọn,” ni Olúwa wí, “torí náà kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé ibẹ̀; ènìyàn ki yóò gbé nínú rè.
- Jeremiah 50:41nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
“Wò ó! Ọ̀wọ́ ọmọ-ogun láti ìhà àríwá; orílẹ̀-èdè ńlá àti àwọn ọba púpọ̀ ni à ń gbé dìde láti òpin ilẹ̀ ayé.
- Jeremiah 50:42nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun, wọ́n burú wọn kò sì ní àánú. Wọ́n n ké bí i rírú omi bí wọ́n ti ṣe ń gun ẹṣin wọn lọ. Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Babeli.
- Jeremiah 50:43nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Ọba Babeli ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wọn sì rọ, ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí.
- Jeremiah 50:44nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Èmi ó lé Babeli kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá. Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀? Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí? Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”
- Jeremiah 50:45nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, gbọ́ ohun tí Olúwa sọ nípa Babeli, ẹni tí ó gbìmọ̀ lòdì sí Babeli: n ó sì pa agbo ẹran wọn run.
- Jeremiah 50:46nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Ní ohùn igbe ńlá pé; a kò Babeli, ilẹ̀ ayé yóò mì tìtì, a sì gbọ́ igbe náà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
- Jeremiah 51:1nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Ohùn ti Olúwa wí nìyìí: “Wò ó èmi yóò ru afẹ́fẹ́ apanirun sókè sí Babeli àti àwọn ènìyàn Lebikamai,
- Jeremiah 51:2nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Èmi yóò rán àwọn àjèjì ènìyàn sí Babeli láti fẹ́ ẹ, tí yóò sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di òfo; wọn yóò takò ó ní gbogbo ọ̀nà ní ọjọ́ ìparun rẹ̀.
- Jeremiah 51:3nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Má ṣe jẹ́ kí tafàtafà yọ ọfà rẹ̀, jáde tàbí kí ó di ìhámọ́ra rẹ̀. Má ṣe dá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí; pátápátá ni kí o pa àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.
- Jeremiah 51:4nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Gbogbo wọn ni yóò ṣubú ní Babeli, tí wọn yóò sì fi ara pa yánnayànna ní òpópónà.
- Jeremiah 51:5nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Nítorí pé Juda àti Israẹli ni Ọlọ́run wọn tí í ṣe Olúwa àwọn ọmọ-ogun, kò gbàgbọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ilé wọn kún fún kìkì ẹ̀bi níwájú ẹni mímọ́ Israẹli.
- Jeremiah 51:6nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
“Sá kúrò ní Babeli! Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe ṣègbé torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Àsìkò àti gbẹ̀san Olúwa ni èyí; yóò sán fún òun gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́.
- Jeremiah 51:7nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Ife wúrà ni Babeli ní ọwọ́ Olúwa; ó sọ gbogbo ayé di ọ̀mùtí. Gbogbo orílẹ̀-èdè mu ọtí rẹ̀, wọ́n sì ti ya òmùgọ̀ kalẹ̀.
- Jeremiah 51:8nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Babeli yóò ṣubú lójijì, yóò sì fọ́. Ẹ hu fun un! Ẹ mú ìkunra fún ìrora rẹ, bóyá yóò le wo ọ́ sàn.
- Jeremiah 51:9nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
“ ‘À bá ti wo Babeli sàn, ṣùgbọ́n kò lè sàn, ẹ jẹ́ kí a fi sílẹ̀, kí oníkálùkù lọ sí ilẹ̀ rẹ̀ torí ìdájọ́ rẹ̀ tó gòkè, ó ga àní títí dé òfúrufú.’
- Jeremiah 51:10nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
“ ‘Olúwa ti dá wa láre, wá jẹ́ kí a sọ ọ́ ní Sioni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wa ti ṣe.’
- Jeremiah 51:11nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
“Ṣe ọfà rẹ ní mímú, mú àpáta! Olúwa ti ru ọba Media sókè, nítorí pé ète rẹ̀ ni láti pa Babeli run. Olúwa yóò gbẹ̀san, àní ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.
- Jeremiah 51:12nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Gbé àsíá sókè sí odi Babeli! Ẹ ṣe àwọn ọmọ-ogun gírí, ẹ pín àwọn olùṣọ́ káàkiri, ẹ ṣètò àwọn tí yóò sá pamọ́ Olúwa! Yóò gbé ète rẹ̀ jáde, òfin rẹ̀ sí àwọn ará Babeli.
- Jeremiah 51:13nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀, tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé, àní àsìkò láti ké ọ kúrò!
- Jeremiah 51:14nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra fún ara rẹ̀, Èmi yóò fún ọ ní ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ eṣú, wọn yóò yọ ayọ̀, ìṣẹ́gun lórí rẹ.
- Jeremiah 51:15nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
“Ó dá ilẹ̀ nípa agbára rẹ̀, o dá ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, o sì tẹ́ ọ̀run pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀.
- Jeremiah 51:16nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ará omi ọ̀run hó ó mú kí òfúrufú ru sókè láti ìpẹ̀kun ayé. Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò, ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti ilé ìṣúra rẹ̀.
- Jeremiah 51:17nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
“Olúkúlùkù ènìyàn ni kò lọ́pọlọ tí kò sì ní ìmọ̀, olúkúlùkù alágbẹ̀dẹ ni a kó ìtìjú bá nípa òrìṣà rẹ̀. Àwọn ère rẹ jẹ́ ẹ̀tàn; wọn kò ní èémí nínú.