- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Daniẹli 5:12nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Ọkùnrin náà ni Daniẹli ẹni tí ọba ń pè ní Belṣassari, ó ní ẹ̀mí tí ó tayọ, ìmọ̀ àti òye, àti agbára láti túmọ̀ àlá, ó máa ń ṣe àlàyé àlá àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá da ojú rú, ránṣẹ́ pè é, yóò sì sọ nǹkan tí àkọsílẹ̀ ìwé náà túmọ̀ sí.”
- Daniẹli 5:13nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni a mú Daniẹli wá síwájú ọba, ọba sì sọ fún un wí pé, “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan lára àwọn tí baba mi mú ní ìgbèkùn láti Juda!
- Daniẹli 5:14nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Mo ti gbọ́ wí pé ẹ̀mí ọlọ́run ń gbé inú rẹ àti wí pé ìwọ ní ojú inú, òye, àti ọgbọ́n tí ó tayọ.
- Daniẹli 5:15nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
A ti mú àwọn amòye àti àwọn awòràwọ̀ wá sí iwájú mí kí wọn ba à le è wá ka àkọsílẹ̀ yìí kí wọn sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ ohun tí ó jẹ́.
- Daniẹli 5:16nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ wí pé, ìwọ lè sọ ìtumọ̀, àti wí pé o lè yanjú àwọn ìṣòro tó lágbára. Tí o bá lè ka àkọsílẹ̀ ìwé yìí kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, a ó fi aṣọ elése àlùkò wọ̀ ọ́ pẹ̀lú ẹ̀gbà wúrà ni a ó fi sí ọ lọ́rùn, a ó sì fi ọ́ ṣe olórí kẹta ní ìjọba mi.”
- Daniẹli 5:17nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Daniẹli dá ọba lóhùn wí pé, “Fi ẹ̀bùn rẹ pamọ́ fún ara rẹ, tàbí kí o fún ẹlòmíràn. Síbẹ̀ èmi yóò ka àkọsílẹ̀ náà fún ọba, èmi yóò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.
- Daniẹli 5:18nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
“Ìwọ ọba, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo fún Nebukadnessari baba rẹ ní ìjọba, títóbi ògo àti ọlá.
- Daniẹli 5:19nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Nítorí ipò ńlá tí a fi fún un, gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo fi ń páyà tí wọ́n sì ń bẹ̀rù rẹ̀. Ó ń pa àwọn tí ó bá wù ú, ó sì ń dá àwọn tí ó bá wù ú sí, ó ń gbé àwọn tí ó bá wù ú ga, ó sì ń rẹ àwọn tí ó bá wù ú sílẹ̀.
- Daniẹli 5:20nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn rẹ̀ ga, tí ó sì le koko. Ó bẹ̀rẹ̀ sí i hùwà ìgbéraga, a mú u kúrò lórí ìtẹ́ ọba rẹ̀, a sì gba ògo rẹ̀ kúrò.
- Daniẹli 5:21nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
A lé e kúrò láàrín ènìyàn, a sì fún un ní ọkàn ẹranko; ó sì ń gbé pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì ń jẹ koríko bí i ti màlúù; ìrì ọ̀run ṣì sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí tó fi mọ̀ pé, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ń jẹ ọba lórí ìjọba ọmọ ènìyàn, òun sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.
- Daniẹli 5:22nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
“Ṣùgbọ́n ìwọ ọmọ rẹ̀, Belṣassari, ìwọ kò rẹ ara à rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ mọ nǹkan wọ̀nyí.
- Daniẹli 5:23nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Dípò èyí, ìwọ gbé ara à rẹ ga sí Olúwa ọ̀run, a mú ohun èlò inú tẹmpili rẹ̀ wá sí iwájú rẹ, ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlè rẹ fi ń mu wáìnì. Ìwọ ń yin àwọn òrìṣà fàdákà àti wúrà, idẹ, irin, igi àti ti òkúta, èyí tí kò lè ríran, tí kò le è gbọ́rọ̀ tàbí ní òye nǹkan kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò bu ọlá fún Ọlọ́run ẹni tó ni ẹ̀mí rẹ lọ́wọ́, tí ó sì mọ gbogbo ọ̀nà rẹ.
- Daniẹli 5:24nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, ó rán ọwọ́ tí ó kọ àkọlé yìí.
- Daniẹli 5:25nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
“Èyí ni àkọlé náà tí a kọ: Mene, mene, tekeli, peresini.
- Daniẹli 5:26nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
“Èyí ni nǹkan tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí: “Mene: Ọlọ́run ti ṣírò ọjọ́ ìjọba rẹ. Ó sì ti mú u wá sí òpin.
- Daniẹli 5:27nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
“Tekeli: A ti gbé ọ lórí òsùwọ̀n, ìwọ kò sì tó ìwọ̀n.
- Daniẹli 5:28nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
“Peresini: A ti pín ìjọba rẹ a sì ti fi fún àwọn Media àti àwọn Persia.”
- Daniẹli 5:29nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Belṣassari pàṣẹ pé kí a wọ Daniẹli ní aṣọ elése àlùkò, kí a sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, a sì kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí kẹta ní ìjọba rẹ̀.
- Daniẹli 5:30nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni a pa Belṣassari, ọba àwọn ara Kaldea.
- Daniẹli 5:31nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Dariusi ará Media sì gba ìjọba nígbà tí ó di ọmọ ọdún méjìlélọ́gọ́ta.
- Daniẹli 6:1nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Ó dára lójú Dariusi láti yan ọgọ́fà àwọn baálẹ̀ sórí ìjọba,
- Daniẹli 6:2nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
pẹ̀lú alákòóso mẹ́ta, Daniẹli sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn, kí àwọn baálẹ̀ lè wá máa jẹ́ ààbọ̀ fún wọn, kí ọba má ba à ní ìpalára.
- Daniẹli 6:3nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Daniẹli ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láàrín àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ nítorí ẹ̀mí tí ó tayọ wà lára rẹ̀ dé bi pé ọba sì ń gbèrò láti fi ṣe olórí i gbogbo ìjọba.
- Daniẹli 6:4nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Nítorí èyí, gbogbo àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ ń gbèrò láti wá ẹ̀ṣẹ̀ kà sí Daniẹli lọ́rùn nínú ètò ìṣèjọba rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan kà sí i lọ́rùn, wọn kò rí ìwà ìbàjẹ́ kankan tí ó ṣe, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ kò sì ní ìwà ìjáfara.
- Daniẹli 6:5nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Nígbẹ̀yìn ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí sọ wí pé, “Àwa kò ní rí ìdí kankan láti kà ẹ̀ṣẹ̀ sí Daniẹli lọ́rùn, àfi èyí tí ó bá ní í ṣe pẹ̀lú òfin Ọlọ́run rẹ̀.”