- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Daniẹli 7:3nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
Ẹranko ńlá mẹ́rin tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, jáde láti inú Òkun náà.
- Daniẹli 7:4nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
“Ẹranko kìn-ín-ní dàbí i kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́ apá a idì, mo sì wò títí a fi fa ìyẹ́ apá rẹ̀ náà tu, a sì gbé e sókè kúrò ní ilẹ̀, a mú kí ó fi ẹsẹ̀ dúró bí ènìyàn, a sì fi àyà ènìyàn fún un.
- Daniẹli 7:5nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
“Mo sì tún rí ẹranko kejì, ó rí bí irú ẹranko ńlá beari kan tí ó ń gbé ilẹ̀ òtútù; o gbé ara sókè ní apá kan, ó sì ní egungun ìhà mẹ́ta láàrín ẹ̀yìn in rẹ̀, wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Dìde kí o sì jẹ ẹran tó pọ̀!’
- Daniẹli 7:6nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
“Lẹ́yìn ìgbà náà, mo tún rí ẹranko kẹta ó rí bí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹranko náà ní ìyẹ́ bí i ti ẹyẹ ní ẹ̀yìn, ó sì ní orí mẹ́rin, a sì fún un ní agbára láti ṣe ìjọba.
- Daniẹli 7:7nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
“Lẹ́yìn èyí, nínú ìran mi ní òru mo tún rí ẹranko kẹrin, ó dẹ́rùbà ni, ó dáyà fo ni, ó sì lágbára gidigidi. Ó ní eyín irin ńlá; ó ń jẹ, ó sì ń fọ́ túútúú, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tókù mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko ti ìṣáájú, ó sì ní ìwo mẹ́wàá.
- Daniẹli 7:8nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
“Bí mo ṣe ń ronú nípa ìwo náà, nígbà náà ni mo rí ìwo mìíràn, tí ó kéré tí ó jáde wá ní àárín wọn; mẹ́ta lára àwọn ìwo ti àkọ́kọ́ sì fàtu níwájú u rẹ̀. Ìwo yìí ní ojú bí i ojú ènìyàn àti ẹnu tí ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga.
- Daniẹli 7:9nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
“Bí mo ṣe ń wò, “a gbé ìtẹ́ ọba kan kalẹ̀, ẹni ìgbàanì jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀. Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú; irun orí rẹ̀ funfun bí òwú, ìtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná. Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná.
- Daniẹli 7:10nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
Odò iná ń sàn, ó ń jáde ní iwájú rẹ̀ wá. Àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un; ọ̀nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún nígbà ẹgbàárùn-ún dúró níwájú rẹ̀. Àwọn onídàájọ́ jókòó, a sì ṣí ìwé wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀.
- Daniẹli 7:11nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
“Nígbà náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ní wò, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga tí ìwo náà ń sọ, mo wò títí a fi pa ẹranko náà, a sì pa á run, a sì jù ú sínú iná tí ń jó.
- Daniẹli 7:12nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
A sì gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn ẹranko yòókù, ṣùgbọ́n a fún wọn láààyè láti wà fún ìgbà díẹ̀.
- Daniẹli 7:13nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
“Nínú ìran mi ní òru mo wò, mo rí ẹnìkan tí ó dúró sí iwájú u mi, ó rí bí ọmọ ènìyàn, ó ń bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ ọ̀run, ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ ẹni ìgbàanì, a sì mú u wá sí iwájú rẹ̀.
- Daniẹli 7:14nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
A sì fi ìjọba, ògo àti agbára ilẹ̀ ọba fún un; gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo wọn wólẹ̀ fún un. Ìjọba rẹ̀, ìjọba ayérayé ni, èyí tí kò le è kọjá, ìjọba rẹ̀ kò sì le è díbàjẹ́ láéláé.
- Daniẹli 7:15nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
“Ọkàn èmi Daniẹli, dàrú, ìran tí ó wá sọ́kàn mi dẹ́rùbà mí.
- Daniẹli 7:16nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
Mo lọ bá ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀, mo sì bi í léèrè òtítọ́ ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí. “Ó sọ fún mi, ó sì túmọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún mi:
- Daniẹli 7:17nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
‘Àwọn ẹranko ńlá mẹ́rin yìí, ni ìjọba mẹ́rin tí yóò dìde ní ayé.
- Daniẹli 7:18nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n, ẹni mímọ́ ti Ọ̀gá-ògo ni yóò gba ìjọba náà, yóò sì jogún un rẹ títí láé àti títí láéláé.’
- Daniẹli 7:19nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
“Nígbà náà, ni mo fẹ́ mọ ìtumọ̀ òtítọ́ ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí àwọn yòókù, èyí tí ó dẹ́rùba ni gidigidi, tí ó ní eyín irin àti èékánná idẹ, ẹranko tí ó ń run tí ó sì ń pajẹ, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tókù mọ́lẹ̀.
- Daniẹli 7:20nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni mo sì fẹ́ mọ̀ nípa ìwo mẹ́wàá orí rẹ̀ àti nípa ìwo yòókù tí ó jáde, nínú èyí tí mẹ́ta lára wọn ṣubú, ìwo tí ó ní ojú, tí ẹnu rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga.
- Daniẹli 7:21nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
Bí mo ṣe ń wò, ìwo yìí ń bá àwọn ènìyàn mímọ́ jagun, ó sì borí i wọn,
- Daniẹli 7:22nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
títí ẹni ìgbàanì fi dé, ó sì ṣe ìdájọ́ ìdáláre fún àwọn ẹni mímọ́ Ọ̀gá-ògo, àsìkò náà sì dé nígbà tí àwọn ẹni mímọ́ náà jogún ìjọba.
- Daniẹli 7:23nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
“Ó ṣe àlàyé yìí fún mi pé, ‘Ẹranko kẹrin ni ìjọba kẹrin tí yóò wà ní ayé. Yóò yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ìjọba yòókù yóò sì pa gbogbo ayé run, yóò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, yóò sì fọ́ ọ́ sí wẹ́wẹ́.
- Daniẹli 7:24nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
Ìwo mẹ́wàá ni ọba mẹ́wàá tí yóò wá láti inú ìjọba yìí. Lẹ́yìn tí wọn ní ọba mìíràn yóò dìde, ti yóò yàtọ̀ sí tí àwọn ti ìṣáájú, yóò sì borí ọba mẹ́ta.
- Daniẹli 7:25nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
Yóò sọ̀rọ̀ odi sí Ọ̀gá-ògo, yóò sì pọ́n ẹni mímọ́ lójú, yóò sì gbèrò láti yí ìgbà àti òfin padà. A ó fi àwọn ẹni mímọ́ lé e lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀, ní ọdún méjì àti ààbọ̀.
- Daniẹli 7:26nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
“ ‘Ṣùgbọ́n àwọn onídàájọ́ yóò jókòó, nígbà náà ni a ó gba agbára rẹ̀, a ó sì pa á rùn pátápátá títí ayé.
- Daniẹli 7:27nǹkan bí 555 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, ni a ó gba ìjọba, agbára àti títóbi ìjọba rẹ̀ ní abẹ́ gbogbo ọ̀run, a ó sì fi fún àwọn ẹni mímọ́, àwọn ènìyàn Ọ̀gá-ògo. Ìjọba rẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba títí ayé, gbogbo aláṣẹ ni yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí i, wọn yóò sì máa sìn ín.’