Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Sinai & The Law

God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.

1,657 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lefitiku 14:37nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Yóò yẹ ààrùn náà wò, bí ààrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa àmì àwọ̀ ewé tàbí àmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ.

  2. Lefitiku 14:38nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àlùfáà yóò jáde kúrò nínú ilé náà, yóò sì ti ìlẹ̀kùn ilé náà pa fún ọjọ́ méje.

  3. Lefitiku 14:39nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àlùfáà yóò padà wá yẹ ilé náà wò ní ọjọ́ keje. Bí ààrùn náà bá ti tàn ká ara ògiri.

  4. Lefitiku 14:40nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àlùfáà yóò pàṣẹ kí a yọ àwọn òkúta tí ààrùn náà ti bàjẹ́ kúrò kí a sì kó wọn dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú.

  5. Lefitiku 14:41nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Yóò sì mú kí wọ́n ha ògiri inú ilé náà yíká. Gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé náà tí ó ti ha ni kí wọ́n kó dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú náà.

  6. Lefitiku 14:42nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Òkúta mìíràn ni kí wọ́n fi dípò àwọn tí a ti yọ dànù, kí wọ́n sì rẹ́ ilé náà pẹ̀lú àwọn ohun ìrẹ́lé tuntun.

  7. Lefitiku 14:43nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Bí ààrùn yìí bá tún farahàn lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta wọ̀nyí tí a sì ti ha ilé náà ti a sì tún rẹ́ ẹ.

  8. Lefitiku 14:44nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àlùfáà yóò tún lọ yẹ̀ ẹ́ wò bí ààrùn náà bá tún gbilẹ̀ sí i nínú ilé náà: ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí, ilé náà jẹ́ aláìmọ́.

  9. Lefitiku 14:45nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wíwó ni kí a wó o, gbogbo òkúta ilé náà, àwọn igi àti gbogbo ohun tí a fi rẹ́ ẹ ni kí a kó jáde nínú ìlú sí ibi tí a kà sí àìmọ́.

  10. Lefitiku 14:46nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Ẹni tí ó bá wọ inú ilé náà lẹ́yìn tí a ti tì í, yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

  11. Lefitiku 14:47nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹni tí ó bá sùn nínú ilé náà tàbí tí ó bá jẹun nínú rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀.

  12. Lefitiku 14:48nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Bí àlùfáà bá wá yẹ̀ ẹ́ wò tí ààrùn náà kò gbilẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tí a ti rẹ́ ilé náà: kí àlùfáà pe ilé náà ní mímọ́, torí pé ààrùn náà ti lọ.

  13. Lefitiku 14:49nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Láti sọ ilé yìí di mímọ́. Àlùfáà yóò mú ẹyẹ méjì àti igi kedari òdòdó àti hísópù.

  14. Lefitiku 14:50nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Yóò sì pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ nínú ìkòkò amọ̀.

  15. Lefitiku 14:51nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Kí ó ri igi kedari, hísópù, òdòdó àti ààyè ẹyẹ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ òkú ẹyẹ àti omi tí ó mọ́ náà kí ó fi wọ́n ilẹ̀ náà lẹ́ẹ̀méje.

  16. Lefitiku 14:52nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Yóò fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà, omi tí ó mọ́, ààyè ẹyẹ, igi kedari, hísópù àti òdòdó sọ ilé náà di mímọ́.

  17. Lefitiku 14:53nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Kí àlùfáà ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ lẹ́yìn ìlú. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún ilé náà. Ilé náà yóò sì mọ́.”

  18. Lefitiku 14:54nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún èyíkéyìí ààrùn àwọ̀ ara tí ó le è ràn ká, fún làpálàpá,

  19. Lefitiku 14:55nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    àti fún ẹ̀tẹ̀ nínú aṣọ, àti ti ilé,

  20. Lefitiku 14:56nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    fún ara wíwú, fún èélá àti ibi ara tí ó ń dán yàtọ̀.

  21. Lefitiku 14:57nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Láti mú kí a mọ̀ bóyá nǹkan mọ́ tàbí kò mọ́. Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún ààrùn àwọ̀ ara tí ó ń ràn ká àti ẹ̀tẹ̀.

  22. Lefitiku 15:1nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,

  23. Lefitiku 15:2nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Ẹ bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, kí ẹ wí fún wọn pé, ‘Bí ìsunjáde bá ń jáde lára ọkùnrin kan lójú ara, ìsunjáde náà jẹ́ àìmọ́.

  24. Lefitiku 15:3nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Yálà ó ń jáde léraléra tàbí ó dúró, èyí yóò sọ ọ́ di aláìmọ́. Báyìí ni ìsunjáde rẹ̀ ṣe le è sọ ọ́ di aláìmọ́:

  25. Lefitiku 15:4nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “ ‘Gbogbo ibùsùn tí irú ẹni tí ó ní ìsunjáde náà bá sùn di àìmọ́.