- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446 BC
Sinai & The Law
God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Lefitiku 14:12nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Kí àlùfáà mú ọ̀kan nínú àwọn àgbò àti lógù òróró kí ó sì fi rú ẹbọ ẹ̀bi. Kí ó sì fì wọ́n níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì.
- Lefitiku 14:13nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Kí ó pa àgbò náà ní ibi mímọ́ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun. Bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi náà jẹ́ ti àlùfáà: ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
- Lefitiku 14:14nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Kí àlùfáà mú nínú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi náà kí ó fi sí etí ọ̀tún ẹni náà tí a ó wẹ̀mọ́, kí ó tún fi sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti orí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.
- Lefitiku 14:15nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Àlùfáà yóò sì mú díẹ̀ nínú lógù òróró, yóò sì dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀.
- Lefitiku 14:16nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Yóò sì ti ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ bọ inú òróró àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, yóò sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ níwájú Olúwa nígbà méje.
- Lefitiku 14:17nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Àlùfáà yóò mú lára òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ yóò fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí à ó wẹ̀mọ́, lórí ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi.
- Lefitiku 14:18nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Àlùfáà yóò fi òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí a ó wẹ̀mọ́, yóò sì ṣe ètùtù fún un níwájú Olúwa.
- Lefitiku 14:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Àlùfáà yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yóò ṣe ètùtù fún ẹni tí a ó wẹ̀ kúrò nínú àìmọ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà àlùfáà yóò pa ẹran ọrẹ ẹbọ sísun.
- Lefitiku 14:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Kí àlùfáà kí ó sì rú ẹbọ sísun, àti ẹbọ ohun jíjẹ lórí pẹpẹ, kí àlùfáà kí ó sì ṣe ètùtù fún un, òun yóò sì di mímọ́.
- Lefitiku 14:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Bí ẹni náà bá jẹ́ tálákà tí kò sì le è kó gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, kí ó mú ọ̀dọ́ àgbò kan bí ẹbọ ẹ̀bi, tí yóò fì, láti ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára, a pò mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ òsùwọ̀n lógù òróró
- Lefitiku 14:22nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
àti àdàbà méjì tàbí ẹyẹlé méjì èyí tí agbára rẹ̀ ká, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun.
- Lefitiku 14:23nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Kí ó mú wọn wá ní ọjọ́ kẹjọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ síwájú àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa.
- Lefitiku 14:24nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Àlùfáà náà yóò sì mú ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú lógù òróró yóò sì fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì.
- Lefitiku 14:25nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Kí ó pa ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi kí ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kí ó fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún.
- Lefitiku 14:26nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Àlùfáà yóò sì da díẹ̀ lára òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀.
- Lefitiku 14:27nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Yóò sì fi ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ wọ́n òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀ nígbà méje níwájú Olúwa.
- Lefitiku 14:28nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Àlùfáà yóò sì mú lára òróró ọwọ́ rẹ̀ sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ní ibi kan náà tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi sí.
- Lefitiku 14:29nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Kí àlùfáà fi ìyókù nínú òróró ọwọ́ rẹ̀ sí orí ẹni náà tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún, láti ṣe ètùtù fún un ní iwájú Olúwa.
- Lefitiku 14:30nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn náà kí ó fi àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé rú ẹbọ níwọ̀n tí agbára rẹ̀ mọ.
- Lefitiku 14:31nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù níwájú Olúwa ní ipò ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́.”
- Lefitiku 14:32nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Òfin nìyí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ààrùn ara tí ó le ran tí kò sì lágbára láti rú ẹbọ tí ó yẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ bí a ti fi lélẹ̀.
- Lefitiku 14:33nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé.
- Lefitiku 14:34nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fi fún yín ní ìní, tí mo sì fi ààrùn ẹ̀tẹ̀ sínú ilé kan ní ilẹ̀ ìní yín.
- Lefitiku 14:35nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Kí ẹni tí ó ní ilé náà lọ sọ fún àlùfáà pé, ‘Èmi tí rí ohun tí ó jọ ààrùn ẹ̀tẹ̀ ní ilé mi.’
- Lefitiku 14:36nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má bá à di àìmọ́. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò.