Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Sinai & The Law

God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.

1,657 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lefitiku 15:30nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Kí àlùfáà fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún un, níwájú Olúwa fún àìmọ́ ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

  2. Lefitiku 15:31nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ẹ ya ará Israẹli sọ́tọ̀ kúrò nínú ohun tí ó ń sọ wọ́n di aláìmọ́, kí wọ́n má bá a kú nínú àìmọ́ wọn nípa bíba ibùgbé mímọ́ mi jẹ́, èyí tí ó wà láàrín wọn.’ ”

  3. Lefitiku 15:32nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún ọkùnrin tí ó ni ìsunjáde fún ẹnikẹ́ni tí a sọ di àìmọ́ nípa ìsunjáde nǹkan ọkùnrin rẹ̀.

  4. Lefitiku 15:33nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Fún obìnrin ní nǹkan oṣù rẹ̀, fún ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ní ìsunjáde, àti fún ọkùnrin tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin tí ó jẹ́ aláìmọ́.

  5. Lefitiku 16:1nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose lẹ́yìn ikú àwọn ọmọ Aaroni méjèèjì tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n súnmọ́ Olúwa.

  6. Lefitiku 16:2nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Kìlọ̀ fún Aaroni arákùnrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wá nígbà gbogbo sí Ibi Mímọ́ Jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa ní ibi tí àpótí ẹ̀rí àti ìtẹ́ àánú wà, kí ó má ba à kú nítorí pé Èmi ó farahàn nínú ìkùùkuu lórí ìtẹ́ àánú.

  7. Lefitiku 16:3nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Báyìí ni Aaroni yóò ṣe máa wá sí Ibi Mímọ́ Jùlọ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò fún ẹbọ sísun.

  8. Lefitiku 16:4nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Òun yóò sì wọ aṣọ funfun mímọ́ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ funfun, yóò sì fi àmùrè funfun mímọ́ dì í, yóò sì dé fìlà funfun, àwọn aṣọ mímọ́ nìwọ̀nyí. Òun yóò sì fi omi wẹ̀, kí ó tó wọ̀ wọ́n.

  9. Lefitiku 16:5nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Òun yóò sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì láti ọ̀dọ̀ gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli láti fi ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n, àti àgbò kan fún ẹbọ sísun.

  10. Lefitiku 16:6nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Aaroni yóò sì fi akọ màlúù rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ èyí tí ṣe ti ara rẹ̀ òun yóò sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀.

  11. Lefitiku 16:7nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn náà yóò sì mú ewúrẹ́ méjì náà wá sí iwájú Olúwa ní ibi ìlẹ̀kùn àgọ́ ìpàdé.

  12. Lefitiku 16:8nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Aaroni yóò sì dìbò ní ti àwọn ewúrẹ́ méjèèjì náà, ìbò àkọ́kọ́ fún ti Olúwa, àti èkejì fún ewúrẹ́ ìpààrọ̀.

  13. Lefitiku 16:9nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Aaroni yóò sì mú ewúrẹ́ tí ìbò Olúwa mú, yóò sì fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

  14. Lefitiku 16:10nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ewúrẹ́ tí ìbò bá mú gẹ́gẹ́ bí ewúrẹ́ ìpààrọ̀ ni a ó mú wá láààyè síwájú Olúwa láti fi ṣe ètùtù sí i àti láti jẹ́ kí ó lọ lọ́fẹ̀ẹ́, sí aginjù.

  15. Lefitiku 16:11nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Aaroni yóò sì mú akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Yóò sì pa akọ màlúù náà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀.

  16. Lefitiku 16:12nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Yóò sì mú àwo tùràrí tí ó kún fún èédú tí a ti sun pẹ̀lú iná láti orí pẹpẹ wá síwájú Olúwa: àti ẹ̀kúnwọ́ méjì tùràrí tí a gún kúnná yóò sì mú un wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa.

  17. Lefitiku 16:13nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Yóò sì fi tùràrí náà lé orí iná níwájú Olúwa: kí èéfín tùràrí náà ba à le bo ìtẹ́ àánú tí ó wà ní orí àpótí ẹ̀rí kí o má ba à kú.

  18. Lefitiku 16:14nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù náà yóò sì fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn, ní iwájú ìtẹ́ àánú, yóò sì fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn nígbà méje níwájú ìtẹ́ àánú.

  19. Lefitiku 16:15nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Nígbà yìí ni yóò pa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà fún àwọn ènìyàn yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa, bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà ni yóò ṣe ti ewúrẹ́ yìí, yóò sì wọ́n ọn sórí ìtẹ́ ètùtù àti síwájú ìtẹ́ ètùtù.

  20. Lefitiku 16:16nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún Ibi Mímọ́ Jùlọ nítorí àìmọ́ àwọn ará Israẹli àti nítorí gbogbo ìrékọjá wọn àti ìṣọ̀tẹ̀ wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbogbo, bákan náà ni yóò sì ṣe fún àgọ́ ìpàdé, èyí tí ó wà láàrín wọn nínú àìmọ́ wọn.

  21. Lefitiku 16:17nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Kí ó má ṣe sí ẹyọ ènìyàn kan nínú àgọ́ ìpàdé nígbà tí òun bá wọ Ibi Mímọ́ Jùlọ lọ láti ṣe ètùtù, títí di ìgbà tí yóò fi jáde lẹ́yìn tí ó ba ṣe ètùtù fúnra rẹ̀ fún ìdílé rẹ̀ àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ Israẹli.

  22. Lefitiku 16:18nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Lẹ́yìn náà òun yóò lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú Olúwa, yóò sì ṣe ètùtù fún pẹpẹ náà. Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti nínú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà, yóò sì fi sí orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwo pẹpẹ náà yíká.

  23. Lefitiku 16:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn náà, òun yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sórí rẹ̀ pẹ̀lú ìka rẹ̀ nígbà méje láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ àti láti sọ ọ́ dí mímọ́ kúrò nínú àìmọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

  24. Lefitiku 16:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Lẹ́yìn ti Aaroni ti parí ṣíṣe ètùtù ti Ibi Mímọ́ Jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ, òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá.

  25. Lefitiku 16:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Aaroni yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Israẹli lé e lórí. Gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà. Yóò sì rán an lọ sí ijù láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà.