Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Sinai & The Law

God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.

1,657 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Eksodu 40:16nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

  2. Eksodu 40:17nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ní ọdún kejì.

  3. Eksodu 40:18nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Mose gbé àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró.

  4. Eksodu 40:19nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

  5. Eksodu 40:20nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó mu ẹ̀rí, ó sì fi sínú àpótí, ó so àwọn òpó mọ́ àpótí náà, ó sì fi àánú bo orí rẹ.

  6. Eksodu 40:21nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  7. Eksodu 40:22nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose gbé tábìlì sínú àgọ́ àjọ sí ìhà àríwá àgọ́ náà lẹ́yìn aṣọ títa,

  8. Eksodu 40:23nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  9. Eksodu 40:24nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó gbé ọ̀pá fìtílà sínú àgọ́ àjọ ní òdìkejì tábìlì ní ìhà gúúsù àgọ́ náà.

  10. Eksodu 40:25nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì tan àwọn fìtílà náà níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  11. Eksodu 40:26nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose gbé pẹpẹ wúrà sínú àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa

  12. Eksodu 40:27nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  13. Eksodu 40:28nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì ta aṣọ títa sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà.

  14. Eksodu 40:29nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  15. Eksodu 40:30nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó gbé agbada sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, ó sì pọn omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀,

  16. Eksodu 40:31nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lò ó láti fi wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn.

  17. Eksodu 40:32nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  18. Eksodu 40:33nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose sì gbé àgbàlá tí ó yí àgọ́ náà kà ró àti pẹpẹ, ó sì ta aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà sí àgbàlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe parí iṣẹ́ náà.

  19. Eksodu 40:34nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni àwọsánmọ̀ bo àgọ́ àjọ, ògo Olúwa bo àgọ́ náà.

  20. Eksodu 40:35nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose kò sì lè wọ inú àgọ́ àjọ, nítorí àwọsánmọ̀ wà ní orí àgọ́, ògo Olúwa sì ti kún inú àgọ́ náà.

  21. Eksodu 40:36nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ní gbogbo ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli nígbàkígbà tí a bá ti fa ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sókè kúrò lórí àgọ́, wọ́n máa ń jáde lọ;

  22. Eksodu 40:37nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    ṣùgbọ́n tí àwọsánmọ̀ kò bá gòkè wọn kò ní jáde títí di ọjọ́ tí ó bá gòkè.

  23. Eksodu 40:38nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà àwọsánmọ̀ Olúwa wà lórí àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọsánmọ̀ ní alẹ́, ní ojú gbogbo ilé Israẹli ní gbogbo ìrìnàjò wọn.

  24. Lefitiku 1:1nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì pe Mose, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú àgọ́ àjọ. Ó wí pé,

  25. Lefitiku 1:2nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sì wí fún wọn pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, kí ọrẹ ẹbọ yín jẹ́ ẹran ọ̀sìn láti inú agbo ẹran tàbí láti inú ọ̀wọ́ ẹran.