- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 48–96
Letters to the Churches
Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Heberu 7:17nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí a jẹ́rìí pé: “Ìwọ ni àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ ti Melkisedeki.”
- Heberu 7:18nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí a mú òfin ìṣáájú kúrò nítorí àìlera àti àìlérè rẹ̀.
- Heberu 7:19nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
(Nítorí òfin kò mú ohunkóhun pé), a sì mú ìrètí tí ó dára jù wá nípa èyí tí àwa ń súnmọ́ Ọlọ́run.
- Heberu 7:20nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Níwọ́n bí ó sì ti ṣe pé kì í ṣe ní àìbúra ni. Nítorí àwọn àlùfáà tẹ́lẹ̀ jẹ oyè láìsí ìbúra,
- Heberu 7:21nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
ṣùgbọ́n ti òun jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nígbà tí Ọlọ́run wí fún un pé, “Olúwa búra, kí yóò sì yí padà: ‘Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé.’ ”
- Heberu 7:22nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Níwọ́n bẹ́ẹ̀ ni Jesu ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù.
- Heberu 7:23nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Àti nítòótọ́ àwọn púpọ̀ ní a ti fi jẹ àlùfáà, nítorí wọn kò lè wà títí nítorí ikú.
- Heberu 7:24nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n òun, nítorí tí o wà títí láé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀ ní ipò.
- Heberu 7:25nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà ó sì le gbà wọ́n là pẹ̀lú títí dé òpin, ẹni tí ó bá tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀, nítorí tí o ń bẹ láààyè títí láé láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.
- Heberu 7:26nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí pé irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀ ni o yẹ wá, mímọ́, àìlẹ́gàn, àìléèérí, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a sì gbéga ju àwọn ọ̀run lọ.
- Heberu 7:27nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí kò ní láti máa rú ẹbọ lójoojúmọ́, bí àwọn olórí àlùfáà, fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀ náà, àti lẹ́yìn náà fún tí àwọn ènìyàn; nítorí èyí ni tí ó ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ.
- Heberu 7:28nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí pé òfin a máa fi àwọn ènìyàn tí ó ní àìlera jẹ olórí àlùfáà; ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ ti ìbúra, tí ó ṣe lẹ́yìn òfin, ó fi ọmọ jẹ; ẹni tí a sọ di pípé títí láé.
- Heberu 8:1nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nísinsin yìí, kókó ohun tí à ń sọ nìyí. Àwa ní irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀, tí ó jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọláńlá nínú àwọn ọ̀run,
- Heberu 8:2nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ìránṣẹ́ ibi mímọ́, àti ti àgọ́ tòótọ́, tí Olúwa pa, kì í ṣe ènìyàn.
- Heberu 8:3nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí a fi olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan jẹ láti máa mú ẹ̀bùn wá láti máa rú ẹbọ, nítorí náà ó ṣe pàtàkì fún eléyìí náà láti ní nǹkan tí ó máa fi sílẹ̀.
- Heberu 8:4nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Tí ó bá jẹ́ pé ó wà ní ayé ni, òun kì bá ti jẹ́ àlùfáà, nítorí pé àwọn ọkùnrin tí ó ń fi ẹ̀bùn sílẹ̀ ti wà bí òfin ṣe là á sílẹ̀.
- Heberu 8:5nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ẹni tí ń jọ́sìn nínú pẹpẹ kan tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ àti òjìji ohun tí ń bẹ ní ọ̀run. Ìdí abájọ nìyí tí a fi kìlọ̀ fún Mose nígbà tí ó fẹ́ kọ́ àgọ́, nítorí ó wí pé, “Kíyèsí i, kí ìwọ kí ó ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ wọn, ti a fi hàn ọ́ ni orí òkè.”
- Heberu 8:6nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó ni ọlá jù, níwọ̀n bí o ti jẹ pé alárinà májẹ̀mú tí o dára jù ní i ṣe, èyí tí a fi ṣe òfin lórí ìlérí tí o sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ.
- Heberu 8:7nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ìbá ṣe pé májẹ̀mú ìṣáájú nì kò ní àbùkù, ǹjẹ́ a kì bá ti wá ààyè fún èkejì.
- Heberu 8:8nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí tí ó rí àbùkù lára wọn, ó wí pé, “Ìgbà kan ń bọ̀, ni Olúwa wí, tí Èmi yóò bá ilé Israẹli àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun.
- Heberu 8:9nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú tí mo ti bá àwọn baba baba wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, nítorí wọn kò jẹ́ olóòtítọ́ sí májẹ̀mú mi èmi kò sì ta wọ́n nu, ni Olúwa wí.
- Heberu 8:10nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá lẹ́yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí. Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn, èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn, èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi.
- Heberu 8:11nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀, tàbí olúkúlùkù arákùnrin rẹ̀, pé, ‘Mọ Olúwa,’ nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí, láti kékeré dé àgbà.
- Heberu 8:12nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí pé èmi ó ṣàánú fún àìṣòdodo wọn, àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn lèmi ki yóò sì rántí mọ́.”
- Heberu 8:13nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ní èyí tí ó wí pé, májẹ̀mú títún ó ti sọ ti ìṣáájú di ti láéláé. Ṣùgbọ́n èyí tí ó ń di i ti láéláé tí ó sì ń gbó, o múra àti di asán.