Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Romu 1:26nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ ń yí ìṣẹ̀dá ìbáṣepọ̀ tí ó tọ̀nà, sí èyí tí kò tọ̀nà.

  2. Romu 1:27nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìbálòpọ̀ obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìṣìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí.

  3. Romu 1:28nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe.

  4. Romu 1:29nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àrankàn; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà búburú; wọ́n jẹ́ afọ̀rọ̀kẹ́lẹ́ ba ni jẹ́.

  5. Romu 1:30nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, akórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọràn sí òbí,

  6. Romu 1:31nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgbọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú.

  7. Romu 1:32nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n.

  8. Romu 2:1nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, aláìríwí ni ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́ tí ń dá ni lẹ́jọ́, nítorí nínú ohun tí ìwọ ń ṣe ìdájọ́ ẹlòmíràn, ìwọ ń dá ara rẹ lẹ́bi; nítorí ìwọ tí ń dájọ́ ń ṣe ohun kan náà nínú èyí tí ìwọ ń dá ni lẹ́jọ́.

  9. Romu 2:2nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́ si gbogbo àwọn tí ó ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí.

  10. Romu 2:3nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí bí ìwọ tí ń ṣe ènìyàn lásán bá ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí, tí ìwọ tìkára rẹ ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ ro èyí pé ìwọ o yọ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run bí?

  11. Romu 2:4nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Tàbí ìwọ ń gàn ọrọ̀ oore àti ìpamọ́ra àti sùúrù rẹ̀? Ìwọ kò ha mọ̀ pé oore Ọlọ́run ni ó ń fà ọ́ lọ sì ìrònúpìwàdà?

  12. Romu 2:5nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí líle àti àìronúpìwàdà ọkàn rẹ̀, ìwọ ń to ìbínú jọ fún ara rẹ de ọjọ́ ìbínú àti ìfihàn ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run.

  13. Romu 2:6nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ọlọ́run yóò san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

  14. Romu 2:7nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ẹni tí ń fi sùúrù nínú rere ṣíṣe, wá ògo àti ọlá àti àìdíbàjẹ́ ni yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun fún.

  15. Romu 2:8nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n fún àwọn onímọ̀-tara-ẹni-nìkan, tí wọn kò sì gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọn ń tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọn yóò ní ìrírí ìrunú àti ìbínú rẹ̀.

  16. Romu 2:9nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ìpọ́njú àti ìrora, yóò wà lórí olúkúlùkù ọkàn ènìyàn tí ń hùwà ibi: ti Júù ṣáájú, àti àwọn Helleni pẹ̀lú;

  17. Romu 2:10nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn Helleni pẹ̀lú.

  18. Romu 2:11nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn.

  19. Romu 2:12nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin, àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dá lẹ́jọ́.

  20. Romu 2:13nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni ẹni ìdáláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dá láre.

  21. Romu 2:14nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà ẹ̀dá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin.

  22. Romu 2:15nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsin yìí.

  23. Romu 2:16nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jesu Kristi ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere mi.

  24. Romu 2:17nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálòpọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run,

  25. Romu 2:18nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fọwọ́sí ohun tí ó dára jùlọ, nítorí tí a ti kọ́ ọ ní òfin;