- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1406–1380 BC
Conquest of Canaan
Joshua leads Israel across the Jordan into the promised land, defeating the Canaanite kingdoms one by one.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Joṣua 4:17nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua pàṣẹ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ jáde kúrò nínú odò Jordani.”
- Joṣua 4:18nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Àwọn àlùfáà náà jáde láti inú odò pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa ni orí wọn. Bí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ ẹ wọn tẹ orí ilẹ̀ gbígbẹ ni omi Jordani náà padà sí ààyè e rẹ̀, o sì kún wọ bèbè bí i ti àtẹ̀yìnwá.
- Joṣua 4:19nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìn-ín-ní àwọn ènìyàn náà lọ láti Jordani, wọ́n sì dúró ní Gilgali ní ìlà-oòrùn Jeriko.
- Joṣua 4:20nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Joṣua sì to àwọn òkúta méjìlá tí wọ́n mú jáde ní Jordani jọ ní Gilgali.
- Joṣua 4:21nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ó sì sọ fún àwọn ará Israẹli, “Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè ní ọwọ́ baba wọn pé, ‘Kín ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’
- Joṣua 4:22nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ẹ ó jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé, ‘Israẹli rékọjá odò Jordani ní orí ilẹ̀ gbígbẹ.’
- Joṣua 4:23nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín mú Jordani gbẹ ní iwájú u yín títí ẹ̀yin fi kọjá. Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí Jordani gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Òkun Pupa, nígbà tí ó mú un gbẹ ní iwájú wa títí àwa fi kọjá.
- Joṣua 4:24nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ó ṣe èyí kí gbogbo ayé lè mọ̀ pé ọwọ́ Olúwa ní agbára, àti kí ẹ̀yin kí ó lè máa bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín ní ìgbà gbogbo.”
- Joṣua 5:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà tí gbogbo àwọn ọba Amori ti ìlà-oòrùn Jordani àti gbogbo àwọn ọba Kenaani tí ń bẹ létí òkun gbọ́ bí Olúwa ti mú Jordani gbẹ ní iwájú àwọn ọmọ Israẹli títí ti a fi kọjá, ọkàn wọn pami, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ìgboyà mọ́ láti dojúkọ àwọn ọmọ Israẹli.
- Joṣua 5:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Olúwa wí fún Joṣua pé, “Fi akọ òkúta ṣe abẹ kí o sì kọ àwọn ọmọ Israẹli ní ilà ní ìgbà ẹ̀ẹ̀kejì.”
- Joṣua 5:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua sì ṣe abẹ akọ òkúta, ó sì kọ àwọn ọmọ Israẹli ní ilà, ní Gibiati-Haralotu.
- Joṣua 5:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Wàyí o, ìdí tí Joṣua fi kọ wọ́n nílà nìyìí. Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó ti Ejibiti jáde wá, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun kú ní aginjù ní ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.
- Joṣua 5:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, gbogbo àwọn ọkùnrin tó jáde láti Ejibiti ni a ti kọ ní ilà, síbẹ̀ gbogbo ènìyàn tí a bí nínú aginjù lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní Ejibiti ni wọn kò kọ ní ilà.
- Joṣua 5:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Àwọn ará Israẹli rìn ní aginjù fún ogójì ọdún títí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó tó ogun n jà nígbà tí wọ́n kúrò ni Ejibiti fi kú, nítorí wọn kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa. Nítorí Olúwa ti búra fún wọn pé wọn kò ní rí ilẹ̀ tí òun ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn láti fi fun wa, ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin.
- Joṣua 5:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni ó gbé àwọn ọmọ wọn dìde dípò wọn, àwọn wọ̀nyí sì ni Joṣua kọ ní ilà. Wọ́n wà ní aláìkọlà nítorí a kò tí ì kọ wọ́n ní ilà ní ojú ọ̀nà.
- Joṣua 5:8nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ìgbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà kọ ilà tan, wọ́n dúró ní ibi tí wọ́n wà ní ibùdó títí ilà wọn fi jinná.
- Joṣua 5:9nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ní Olúwa wí fún Joṣua pé, “Ní òní ni mo yí ẹ̀gàn Ejibiti kúrò ní orí yín.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Gilgali títí ó fi di òní yìí.
- Joṣua 5:10nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù náà, nígbà tí wọ́n pàgọ́ ní Gilgali ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko, àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ọdún àjọ ìrékọjá.
- Joṣua 5:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ kejì àjọ ìrékọjá, ní ọjọ́ náà gan an ni, wọ́n jẹ nínú àwọn ìre oko ilẹ̀ náà: àkàrà aláìwú, àti ọkà yíyan.
- Joṣua 5:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Manna náà sì tan ní ọjọ́ kejì tí wọ́n jẹ oúnjẹ tí ilẹ̀ náà mú jáde, kò sì sí manna kankan mọ́ fún àwọn ará Israẹli, ṣùgbọ́n ní ọdún náà wọ́n jẹ ìre oko ilẹ̀ Kenaani.
- Joṣua 5:13nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Joṣua súnmọ́ Jeriko, ó wo òkè ó sì rí ọkùnrin kan tí ó dúró ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú idà ní ọwọ́ rẹ̀. Joṣua sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, “Ǹjẹ́ ìwọ wà fún wa tàbí fún ọ̀tá a wa?”
- Joṣua 5:14nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Kì í ṣe fún èyíkéyìí ó fèsì, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí ogun Olúwa ni mo wá nísinsin yìí.” Nígbà náà ni Joṣua sì wólẹ̀ ní iwájú u rẹ̀ ní ìbẹ̀rù, ó sì bi í léèrè, “Kí ni Olúwa ní í sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?”
- Joṣua 5:15nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Olórí ogun Olúwa sì dá a lóhùn pé, “Bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé ibi tí ìwọ dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀.
- Joṣua 6:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Wàyí o, a ti há Jeriko mọ́lé gágá nítorí àwọn ọmọ Israẹli, ẹnikẹ́ni kò jáde, ẹnikẹ́ni kò sì wọlé.
- Joṣua 6:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Olúwa wí fún Joṣua pé, “Wò ó, mo ti fi Jeriko lé ọ lọ́wọ́ pẹ̀lú ọba rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀.