Fò sí àkóónú

Jerusalem

753 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jerusalem's

31.7700, 35.2300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jerusalem

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó jẹ ọba lórí Israẹli fún ogójì ọdún; ọdún méje ni ó jẹ ọba ní Hebroni, ó sì jẹ ọba ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu.

  2. Nísinsin yìí, Dafidi ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wá láti Kiriati-Jearimu sí ibi tí ó ti pèsè fún un, nítorí ó ti kọ́ àgọ́ fún un ni Jerusalẹmu.

  3. Nígbà náà ni Solomoni sì ti ibi gíga Gibeoni lọ sí Jerusalẹmu láti iwájú àgọ́ ìpàdé. Ó sì jẹ ọba lórí Israẹli.

  4. Solomoni kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ, ó sì ní ẹgbàáje (1,400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó kó pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ ogun àti pẹ̀lú rẹ̀ ni Jerusalẹmu.

  5. Ọba náà ṣe fàdákà àti wúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti wọ́pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti kedari ó pọ̀ bí igi sikamore ní àwọn ẹsẹ̀ òkè.

  6. “Nítorí náà, rán ọkùnrin kan sí mi, tí a kọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà àti idẹ àti irin, àti ní àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti ní àwọ̀ ojú ọ̀run, tí ó jẹ́ onímọ̀ nínú iṣẹ́ igi gbígbẹ́ láti ṣiṣẹ́ ní Juda àti Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn onímọ̀ oníṣọ̀nà tí baba à mi Dafidi pèsè.

  7. Àwa yóò sì gé gbogbo àwọn ìtí igi láti Lebanoni tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú a ó gbé wọn fò lójú omi òkun lọ sí Joppa. Lẹ́yìn náà ìwọ lè kó wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu.”

  8. Nígbà náà, Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu lórí òkè Moria, níbi tí Olúwa ti farahan baba a rẹ̀ Dafidi. Ní orí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi, ibi tí Dafidi pèsè.

  9. Nígbà náà ni Solomoni pe àwọn àgbàgbà Israẹli jọ sí Jerusalẹmu, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan àti àwọn olóyè àwọn ìdílé Israẹli, kí wọn kí ó gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá láti Sioni ìlú Dafidi.

  10. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ti yan Jerusalẹmu, kí orúkọ mi le è wà níbẹ̀, èmi sì ti yan Dafidi láti jẹ ọba lórí Israẹli ènìyàn mi.’

  11. Àti gẹ́gẹ́ bí Baalati àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti gbogbo ìlú fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn ẹṣin rẹ̀ ohunkóhun tí ó bá yẹ ní kókó ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo àyíká agbègbè tí ó ń darí.

  12. Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè tí ó le. Ó dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá kan pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye wúrà, àti òkúta iyebíye, ó wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn rẹ̀.

  13. Solomoni sì ní ẹgbàajì (4,000) ilé fún àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) àwọn ẹṣin, tí ó fi pamọ́ nínú ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ nínú Jerusalẹmu.

  14. Ọba sì sọ fàdákà dàbí òkúta ní Jerusalẹmu, àti igi kedari ni ó sì ṣe bí igi sikamore, tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

  15. Solomoni jẹ ọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo àwọn Israẹli fún ogójì ọdún

  16. Ọba Rehoboamu rán Adoniramu jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúurú, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Rehoboamu, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jerusalẹmu.

  17. Nígbà tí Rehoboamu dé Jerusalẹmu, ó kó ilé Juda àti Benjamini jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n jẹ́ ológun, láti bá Israẹli jà kí ó lè mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀.

  18. Rehoboamu ń gbe ní Jerusalẹmu ó sì kọ́ àwọn ìlú fún olódi ní Juda.

  19. Àwọn ará Lefi fi ìgbèríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Juda àti Jerusalẹmu nítorí Jeroboamu àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà Olúwa.

  20. Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tẹ̀lé àwọn ará Lefi lọ sí Jerusalẹmu láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run baba a wọn.

  21. Nítorí tí wọn kò ṣọ òtítọ́ sí Olúwa. Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu ní ọdún karùn-ún ti ọba Rehoboamu.

  22. Ó fi agbára mú àwọn ìlú ààbò ti Juda, pẹ̀lú wá sí Jerusalẹmu bí ó ti jìnnà tó.

  23. Nígbà náà, wòlíì Ṣemaiah wá sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí Juda tí wọ́n ti péjọ ní Jerusalẹmu nítorí ìbẹ̀rù Ṣiṣaki, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ìwọ ti pa mí tì; nítorí náà èmi náà ti pa yín tì sí ọ̀dọ̀ Ṣiṣaki.”

  24. Nígbà tí Olúwa rí i pé, wọ́n ti rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa yí tọ Ṣemaiah lọ pé, “Níwọ́n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, Èmi kì yóò pa wọ́n ṣùgbọ́n, yóò fún wọn ní ìtúsílẹ̀ tó bá yá. Ìbínú mi kì yóò dà sórí Jerusalẹmu ní ipasẹ̀ Ṣiṣaki.

  25. Nígbà tí Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu, ó gbé àwọn ìṣúra ilé Olúwa, àti àwọn ìṣúra ààfin ọba. Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Solomoni dá.