Fò sí àkóónú

Jerusalem

753 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jerusalem's

31.7700, 35.2300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jerusalem

Sẹ́ nípa ìwé
  1. A ṣe ìkéde ní Juda àti Jerusalẹmu wí pé wọ́n gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa, owó orí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti béèrè lọ́wọ́ Israẹli ní aginjù.

  2. Wọ́n pa ilé Olúwa tì, Ọlọ́run baba a wọn. Wọ́n sì ń sin àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yìí, ìbínú Ọlọ́run dé sórí Juda àti Jerusalẹmu.

  3. Ní òpin ọdún, àwọn ọmọ-ogun Aramu yàn láti dojúkọ Joaṣi; wọ́n gbógun ti Juda àti Jerusalẹmu, wọ́n sì pa gbogbo àwọn aṣáájú àwọn ènìyàn. Wọ́n rán gbogbo àwọn ìkógun sí ọba wọn ní Damasku.

  4. Amasiah jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jehoadani, ó wá láti Jerusalẹmu.

  5. Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Joaṣi ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà Joaṣi mú u wá sí Jerusalẹmu. Ó sì wó ògiri Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ẹnu-ọ̀nà Efraimu sí igun ẹnu-ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí irinwó (400) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn.

  6. Láti ìgbà tí Amasiah ti yípadà kúrò láti máa tẹ̀lé Olúwa, wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jerusalẹmu, ó sì sálọ sí Lakiṣi ṣùgbọ́n, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e lọ sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á síbẹ̀.

  7. Ussiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìléláàádọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekoliah; ó sì wá láti Jerusalẹmu.

  8. Ussiah sì kọ́ ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi ẹnu-bodè igun, àti níbi ẹnu-bodè àfonífojì àti níbi ìṣẹ́po odi ó sì mú wọn le

  9. Ní Jerusalẹmu ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun, iṣẹ́ ọwọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn, láti wà lórí ilé ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára.

  10. Jotamu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì di ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jeruṣa ọmọbìnrin Sadoku.

  11. Ó sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún.

  12. Ahasi sì jẹ́ ẹni ogún ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Gẹ́gẹ́ bí i Dafidi baba rẹ̀ kò sì ṣe ohun rere ní ojú Olúwa.

  13. Nísinsin yìí, ẹ̀yin ń pète láti mú ọkùnrin àti obìnrin Juda àti Jerusalẹmu ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú yín, ẹ̀yin kò ha jẹ̀bi Olúwa Ọlọ́run yín, àní ẹ̀yin?

  14. Ahasi sì kó gbogbo ohun èlò láti ilé Olúwa jọ ó sì kó wọn lọ. Ó sì ti ìlẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tẹ́ pẹpẹ fún ara rẹ̀ ní gbogbo igun Jerusalẹmu.

  15. Ahasi sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Jerusalẹmu ṣùgbọ́n wọn kò mú un wá sínú àwọn isà òkú àwọn ọba Israẹli. Hesekiah ọmọ rẹ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  16. Hesekiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Abijah ọmọbìnrin Sekariah.

  17. Nítorí náà, ìbínú Olúwa ti ru sókè wá sórí Juda àti Jerusalẹmu ó sì ti fi wọ́n ṣe ohun èlò fún wàhálà, àti ìdààmú àti ẹ̀sín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fi ojú rẹ̀ rí i.

  18. Hesekiah sì ránṣẹ́ sí gbogbo Israẹli àti Juda, ó sì kọ ìwé sí Efraimu àti Manase, kí wọn kí ó wá sínú ilé Olúwa ní Jerusalẹmu láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli.

  19. Nítorí tí ọba ti gbìmọ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo ìjọ ènìyàn ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní oṣù kejì.

  20. Nítorí wọn kò lè pa á mọ́ ní àkókò náà, nítorí àwọn àlùfáà kò tí i ya ara wọn sí mímọ́ tó; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò tí ì kó ara wọn jọ sí Jerusalẹmu.

  21. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi àṣẹ kan lélẹ̀, láti kéde ká gbogbo Israẹli láti Beerṣeba àní títí dé Dani, láti wá pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ní Jerusalẹmu: nítorí wọn kò pa á mọ́ ní ọjọ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.

  22. Síbẹ̀ òmíràn nínú àwọn ènìyàn Aṣeri àti Manase àti Sebuluni rẹ̀ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Jerusalẹmu.

  23. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì péjọ ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní oṣù kejì.

  24. Wọ́n sì dìde, wọ́n sì kó gbogbo pẹpẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu lọ, àti gbogbo pẹpẹ tùràrí ni wọ́n kó lọ, wọ́n sì dà wọ́n sí odò Kidironi.

  25. Àwọn ọmọ Israẹli tí a rí ní Jerusalẹmu fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní ọjọ́ méje: àwọn ọmọ Lefi, àti àwọn àlùfáà yin Olúwa lójoojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí Olúwa.