Fò sí àkóónú

Jerusalem

753 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jerusalem's

31.7700, 35.2300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jerusalem

Sẹ́ nípa ìwé
  1. ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jerusalẹmu àti gbogbo ilé ńlá ńlá ni ó dáná sun.

  2. Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀.

  3. Àwọn mẹ́fà wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà. Dafidi sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.

  4. Wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un ní Jerusalẹmu: Ṣimea, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bati-Ṣua ọmọbìnrin Ammieli.

  5. Johanani baba Asariah. (Òhun ni ó sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà nínú ilé Olúwa tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).

  6. A kó Josadaki lẹ́rú nígbà tí Olúwa lé Juda àti Jerusalẹmu kúrò ní ìlú nípasẹ̀ Nebukadnessari.

  7. Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.

  8. Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn ìdílé, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìran wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu.

  9. pẹ̀lú Mikiloti, tí ó jẹ́ baba Ṣimea. Wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.

  10. Àwọn tí ó wá láti Juda láti Benjamini àti láti Efraimu àti Manase tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu jẹ́:

  11. Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn Lefi, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu.

  12. Mikiloti jẹ́ baba Ṣimeamu, àwọn náà ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.

  13. Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde lọ sí Jerusalẹmu (tí ṣe Jebusi). Àwọn Jebusi ara ilẹ̀ náà ń gbé níbẹ̀.

  14. Ní Jerusalẹmu Dafidi mú ọ̀pọ̀ ìyàwó ó sì di baba àwọn ọmọ ọkùnrin púpọ̀ àti ọmọbìnrin.

  15. Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ náà tí wọ́n bí fún un níbẹ̀: Ṣammua, Ṣobabu, Natani, Solomoni,

  16. Dafidi kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní Jerusalẹmu láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún un.

  17. Dafidi mú àpáta wúrà tí àwọn ìjòyè Hadadeseri gbé, ó sì gbé wọn wá sí Jerusalẹmu.

  18. Nígbà ti àwọn ará Ammoni ri pé àwọn ará Siria ń sálọ, àwọn náà sálọ kúrò níwájú arákùnrin rẹ̀ Abiṣai. Wọ́n sì wọ inú ìlú ńlá lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Joabu padà lọ sí Jerusalẹmu.

  19. Ní àkókò àkọ́rọ̀ òjò, ni ìgbà tí àwọn ọba lọ sí ogun, Joabu ṣamọ̀nà àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun. Ó fi ilẹ̀ àwọn ará Ammoni ṣòfò. Ó lọ sí ọ̀dọ̀ Rabba. Ó sì fi ogun dúró tì í. Ṣùgbọ́n Dafidi dúró sí Jerusalẹmu Joabu kọlu Rabba, ó sì fi sílẹ̀ ní ìparun.

  20. Ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ jáde, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ayùn àti ìtulẹ̀ onírin àti àáké. Dafidi ṣe eléyìí sí gbogbo àwọn ará ìlú Ammoni. Nígbà náà, Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ padà sí Jerusalẹmu.

  21. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí tí Joabu. Bẹ́ẹ̀ ni Joabu jáde lọ, ó sì la gbogbo Israẹli já, ó sí dé Jerusalẹmu.

  22. Ọlọ́run sì rán angẹli kan sí Jerusalẹmu láti pa wọ́n run. Ṣùgbọ́n bí angẹli ti ń pa wọ́n run, Olúwa sì wò. Ó sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì wí fún angẹli tí ó pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó ti tó! Dá ọwọ́ rẹ dúró.” Angẹli Olúwa náà sì dúró níbi ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.

  23. Dafidi sì wòkè ó sì rí angẹli Olúwa dúró láàrín ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì nà án sórí Jerusalẹmu. Nígbà náà Dafidi àti àwọn àgbàgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀.

  24. Nítorí pé Dafidi ti sọ pé, “Níwọ̀n ìgbà tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jerusalẹmu títí láéláé,

  25. Dafidi pe gbogbo àwọn oníṣẹ́ ti Israẹli láti péjọ ní Jerusalẹmu. Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà, àwọn alákòóso ìpín nínú iṣẹ́ bí ọba, àwọn alákòóso ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí bíbojútó gbogbo àwọn ẹrù àti ohun ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú ààfin àwọn oníṣẹ́ ààfin, àwọn ọkùnrin alágbára àti gbogbo àwọn ògbójú jagunjagun lápapọ̀.