Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ìwọ sì fi oore tí ìwọ ti ṣe fún mi hàn lónìí: nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti fi ẹ̀mí mi lé ọ lọ́wọ́, ìwọ kò sì pa mí.

  2. Nítorí pé bí ènìyàn bá rí ọ̀tá rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní àlàáfíà bí? Olúwa yóò sì fi ìre san èyí ti ìwọ ṣe fún mi lónìí.

  3. Sì búra fún mi nísinsin yìí ní orúkọ Olúwa, pé, ìwọ kì yóò gé irú-ọmọ mi kúrò lẹ́yìn mi, àti pé, ìwọ kì yóò pa orúkọ mi run kúrò ní ìdílé baba mi.”

  4. Bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni ki Ọlọ́run ó ṣe sí àwọn ọ̀tá Dafidi, bi èmi bá fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú gbogbo èyí tí i ṣe tirẹ̀ títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀.”

  5. Ǹjẹ́ olúwa mi, bi Olúwa ti wà láààyè, àti bí ẹ̀mí rẹ̀ si ti wà láààyè, bi Olúwa sì ti dá ọ dúró láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti láti fi ọwọ́ ara rẹ gba ẹ̀san; ǹjẹ́, kí àwọn ọ̀tá rẹ, àti àwọn ẹni tí ń gbèrò ibi sí olúwa mi rí bi i Nabali.

  6. “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ìrékọjá arábìnrin rẹ jìn ín, nítorí Olúwa yóò sá ṣe ilé òdodo fún olúwa mi, nítorí pé ó ja ogun Olúwa. Nítorí náà kí a má ri ibi kan ni ọwọ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí ó wà láààyè.

  7. Bí ọkùnrin kan bá sì dìde láti máa lépa rẹ, àti máa wá ẹ̀mí rẹ, a ó sì di ẹ̀mí olúwa mi nínú ìdì ìyè lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ; àti ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ ni a ó sì gbọ̀n sọnù gẹ́gẹ́ bí kànnàkànnà jáde.

  8. Yóò sì ṣe, Olúwa yóò ṣe sí olúwa mi gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìre tí ó ti wí nípa tirẹ̀, yóò sì yàn ọ́ ni aláṣẹ lórí Israẹli.

  9. Èyí kì yóò sì jásí ìbànújẹ́ fún ọ, tàbí ìbànújẹ́ ọkàn fún olúwa mi, nítorí pé ìwọ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, tàbí pé olúwa mi gba ẹ̀san fún ara rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí Olúwa ba ṣe oore fún olúwa mi, ǹjẹ́ rántí ìránṣẹ́bìnrin rẹ!”

  10. Dafidi sì wí fún Abigaili pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi.

  11. Nítòótọ́, bí Olúwa Ọlọ́run Israẹli tí ń bẹ, tí ó da mi dúró láti pa ọ́ lára bí kò ṣe pé bí ìwọ ti yára tí ó sì wá pàdé mi, nítòótọ́ kì bá tí kù fún Nabali di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀.”

  12. Ó sì ṣe lẹ́yìn ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́wàá, Olúwa lu Nabali, ó sì kú.

  13. Dafidi sì gbọ́ pé Nabali kú, ó sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí o gbèjà gígàn mi láti ọwọ́ Nabali wá, tí ó sì dá ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró láti ṣe ibi: Olúwa sì yí ìkà Nabali sí orí òun tìkára rẹ̀.” Dafidi sì ránṣẹ́, ó sì ba Abigaili sọ̀rọ̀ láti mú un fi ṣe aya fún ara rẹ̀.

  14. Abiṣai sì wí fún Dafidi pé, “Ọlọ́run ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ lónìí: ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, sá à jẹ́ kí èmi o fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, èmi kì yóò gun un lẹ́ẹ̀méjì.”

  15. Dafidi sì wí fún Abiṣai pé, “Má ṣe pa á nítorí pé ta ni lè na ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni àmì òróró Olúwa kí ó sì wà láìjẹ̀bi?”

  16. Dafidi sì wí pé, “Bí Olúwa tí ń bẹ Olúwa yóò pa á, tàbí ọjọ́ rẹ̀ yóò sì pé tí yóò kú, tàbí òun ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ìjà yóò sì ṣègbé níbẹ̀.

  17. Olúwa má jẹ́ kí èmi na ọwọ́ mi sí ẹni àmì òróró Olúwa. Ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, mú ọ̀kọ̀ náà tí ń bẹ níbi tìmùtìmù rẹ̀, àti ìgò omi kí a sì máa lọ.”

  18. Dafidi sì mú ọ̀kọ̀ náà àti ìgò omi náà kúrò níbi tìmùtìmù Saulu: wọ́n sì bá tiwọn lọ, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí i, tàbí tí ó mọ̀: kò sì sí ẹnìkan tí ó jí; gbogbo wọn sì sùn; nítorí pé oorun èjìká láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ti ṣubú lù wọ́n.

  19. Nǹkan tí ìwọ ṣe yìí kò dára. Bí Olúwa ti ń bẹ, o tọ́ kí ẹ̀yin ó kú, nítorí pé ẹ̀yin kò pa olúwa yín mọ́, ẹni àmì òróró Olúwa. Ǹjẹ́ sì wo ibi tí ọ̀kọ̀ ọba gbé wà, àti ìgò omi tí ó ti wà níbi tìmùtìmù rẹ̀.”

  20. Ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, ọba, olúwa mi, gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. Bí ó bá ṣe Olúwa bá ti rú ọ sókè sí mi, jẹ́ kí òun o gba ẹbọ; ṣùgbọ́n bí o bá sì ṣe pé ọmọ ènìyàn ni, ìfibú ni kí wọn ó jásí níwájú Olúwa; nítorí tí wọn lé mi jáde lónìí kí èmi má ba à ní ìpín nínú ilẹ̀ ìní Olúwa, wí pé, ‘Lọ sin àwọn ọlọ́run mìíràn.’

  21. Ǹjẹ́ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi ó sàn sílẹ̀ níwájú Olúwa; nítorí ọba Israẹli jáde láti wá ẹ̀mí mi bi ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè ńlá.”

  22. Kí Olúwa o san án fún olúkúlùkù bí òdodo rẹ̀ àti bí òtítọ́ rẹ̀: nítorí pé Olúwa tí fi ọ lé mi lọ́wọ́ lónìí, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ nawọ́ mi sí ẹni àmì òróró Olúwa.

  23. Sì wò ó, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí rẹ ti tóbi lónìí lójú mi, bẹ́ẹ̀ ni ki ẹ̀mí mi ó tóbi lójú Olúwa, kí ó sì gbà mí lọ́wọ́ ibi gbogbo.”

  24. Nígbà tí Saulu sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Urimu tàbí nípa àwọn wòlíì.

  25. Saulu sì búra fún un nípa Olúwa pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ìyà kan kì yóò jẹ́ ọ́ nítorí nǹkan yìí.”