Fò sí àkóónú

Absalom

92 ẹsẹ · 23 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Abishalom

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Absalom

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èkejì rẹ̀ sì ni Kileabu, tí Abigaili aya Nabali ará Karmeli bí fún un; ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ tí Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un.

  2. Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Absalomu ọmọ Dafidi ní àbúrò obìnrin kan tí ó ṣe arẹwà, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Tamari; Amnoni ọmọ Dafidi sì fẹ́ràn rẹ̀.

  3. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ ọmọ ọba ń fi ń rù lójoojúmọ́ báyìí? Ǹjẹ́ o kò ní sọ fún mi?” Amnoni sì wí fún un pé, “Èmi fẹ́ Tamari àbúrò Absalomu arákùnrin mi.”

  4. Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bí i léèrè pé, “Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ bá ọ sùn bí? Ǹjẹ́ àbúrò mi, dákẹ́; ẹ̀gbọ́n rẹ ní í ṣe; má fi nǹkan yìí sí ọkàn rẹ.” Tamari sì jókòó ní ìbànújẹ́ ní ilé Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

  5. Absalomu kò sì bá Amnoni sọ nǹkan rere, tàbí búburú, nítorí pé Absalomu kórìíra Amnoni nítorí èyí tí ó ṣe, àní tí ó fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀.

  6. Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Absalomu sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori, èyí tí ó gbé Efraimu, Absalomu sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba.

  7. Absalomu sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.”

  8. Ọba sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má bá à mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un.

  9. Absalomu sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Amnoni ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.” Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.”

  10. Absalomu sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Amnoni àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ.

  11. Absalomu sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Kí ẹ̀yin máa kíyèsi àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Amnoni dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, ‘Kọlu Amnoni,’ kí ẹ sì pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin? Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ.”

  12. Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlùkù gun ìbáaka rẹ̀, wọ́n sì sá.

  13. Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Dafidi pé, “Absalomu pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn.”

  14. Jonadabu ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú, nítorí láti ẹnu Absalomu wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀.

  15. Absalomu sì sá. Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ń ṣọ́nà sì gbé ojú rẹ̀ sókè, o si rí i pé, “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ́ lọ́nà lẹ́yìn rẹ̀ láti ìhà òkè wá.”

  16. Absalomu sì sá, ó sì tọ Talmai lọ, ọmọ Ammihudu, ọba Geṣuri. Dafidi sì ń káàánú nítorí ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́.

  17. Absalomu sì sá, ó sì lọ sí Geṣuri ó sì gbé ibẹ̀ lọ́dún mẹ́ta.

  18. Ọkàn Dafidi ọba sì fà gidigidi sí Absalomu, nítorí tí ó tí gba ìpẹ̀ ní ti Amnoni: ó sá à ti kú.

  19. Joabu ọmọ Seruiah sì kíyèsi i, pé ọkàn ọba sì fà sí Absalomu.

  20. Ọba sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, èmi ó ṣe nǹkan yìí, nítorí náà lọ, kí o sì mú ọmọdékùnrin náà Absalomu padà wá.”

  21. Joabu sì dìde, ó sì lọ sí Geṣuri, ó sì mú Absalomu wá sí Jerusalẹmu.

  22. Ọba sì wí pé, “Jẹ́ kí ó yípadà lọ sí ilé rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó rí ojú mi.” Absalomu sì yípadà sí ilé rẹ̀, kò sì rí ojú ọba.

  23. Kó sì sí arẹwà kan ní gbogbo Israẹli tí à bá yìn bí Absalomu: láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ kò sí àbùkù kan lára rẹ̀.

  24. A sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún Absalomu àti ọmọbìnrin kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari: òun sì jẹ́ obìnrin tí ó lẹ́wà lójú.

  25. Absalomu sì gbé ni ọdún méjì ní Jerusalẹmu kò sì rí ojú ọba.