- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Òwe23
Listen to this chapter
0:00
0:00
Ìṣọ́ra nígbà jíjẹun pẹ̀lú àwọn alákòóso
1
Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun, kíyèsi ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi.
2
Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun, bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn.
3
Má ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀: nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni.
Òmùgọ̀ lílé ọrọ̀
4
Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀: ṣíwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ.
5
Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí? Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀, ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run.
Yẹra fún alálejò oníwọ̀ra àti olùkórìíra
6
Má ṣe jẹ oúnjẹ ẹni tí ó háwọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀.
7
Nítorí pé bí ẹni tí ń ṣírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí: “Máa jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó ń wí fún ọ; ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ.
8
Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde, ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù.
Ọgbọ́n fún àwọn olùgbọ́ oríṣiríṣi
9
Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè; nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ.
Bíbọ́wọ̀ fún ààlà àti àwọn òtòṣì
10
Má ṣe ṣí ààlà àtijọ́ kúrò; má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba.
11
Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára; yóò gba ìjà wọn jà sí ọ.
Ìfaramọ́ ẹ̀kọ́
12
Fi àyà sí ẹ̀kọ́, àti etí rẹ sí ọ̀rọ̀-ìmọ̀.
13
Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé, nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú.
14
Bí ìwọ fi pàṣán nà án, ìwọ ó sì gbà ọkàn rẹ̀ là kúrò ní ọ̀run àpáàdì.
15
Ọmọ mi, bí ọkàn rẹ bá gbọ́n, ọkàn mi yóò yọ̀, àní èmi pẹ̀lú.
16
Inú mi yóò sì dùn nígbà tí ètè rẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀ títọ́.
Má ṣe ṣe ìlara àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀
17
Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù Olúwa, ní ọjọ́ gbogbo.
18
Nítorí pé ìgbẹ̀yìn ń bẹ nítòótọ́; ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò.
Yẹra fún ìmutípara àti jíjẹ àjẹjù
19
Gbọ́, ìwọ ọmọ mi, kí o sì gbọ́n, kí o sì máa tọ́ àyà rẹ sí ọ̀nà títọ́.
20
Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí; àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun;
21
nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà; ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ.
22
Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ, má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó.
23
Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á; ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́ àti òye.
24
Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi: ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n, yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀.
25
Jẹ́ kí baba rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀, sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn.
Ewu àgbèrè
26
Ọmọ mi, fi àyà rẹ fún mi, kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ ní inú dídùn sí ọ̀nà mi.
27
Nítorí pé panṣágà obìnrin ọ̀gbun jíjìn ni; àti àjèjì obìnrin kànga híhá ni.
28
Òun á sì ba ní bùba bí olè, a sì sọ àwọn olùrékọjá di púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn.
Àkójọ ìbànújẹ́ ìmutípara
29
Ta ni ó ni òsì? Ta ni ó ni ìbànújẹ́? Ta ni ó ni ìjà? Ta ni ó ni asọ̀? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí?
30
Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí wáìnì; àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò.
31
Ìwọ má ṣe wò ọtí wáìnì nígbà tí ó pọ́n, nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago, tí a gbé e mì, tí ó ń dùn.
32
Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò, a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.
33
Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin, àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ̀ àyídáyidà.
34
Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárín Òkun, tàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀.
35
Ìwọ ó sì wí pé, “Wọ́n lù mí; kò dùn mí; wọ́n lù mí, èmi kò sì mọ̀: nígbà wo ni èmi ó jí? Èmi ó tún máa wá òmíràn láti mu.”
Use ← → arrow keys to navigate
Settings
Reading Style
Typeface
Font Size px
Reading Width chars
Options
Study Note