Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Warfare of Saints

107 ẹsẹ · 73 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”

  2. Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́ kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.

  3. Ti Dafidi. Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi; ta ni èmi yóò bẹ̀rù? Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?

  4. Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi láti jẹ ẹran-ara mi, àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi, wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

  5. Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi, ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù; bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi, nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.

  6. Dúró de Olúwa; kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le àní dúró de Olúwa.

  7. Ti Dafidi. Olúwa, gbógun ti àwọn tí ń gbóguntì mí; kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà!

  8. Di asà àti àpáta mú, kí o sì dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi!

  9. Fa idà àti ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojúkọ àwọn tí ń lé mi. Sọ fún ọkàn mi pé, “Èmi ni ìgbàlà rẹ.”

  10. Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.

  11. Àwọn ọ̀tá mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́, àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.

  12. Wò ó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí! Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi kì í ṣe nítorí ìrékọjá mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, Olúwa.

  13. Àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ní ìwọ fi ọ̀págun fún kí a lè fihàn nítorí òtítọ́. Sela.

  14. Ìwọ tì mí gidigidi kí n lè ṣubú, ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́.

  15. Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi, ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.

  16. Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogun àti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀, ni yóò wà fún ìjóná, àti ohun èlò iná dídá.

  17. Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù, kúrò ní ojú gbogbo wọn, Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé. Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

  18. Ṣùgbọ́n àwọn òkú yín yóò wà láààyè ara wọn yóò dìde. Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀, dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀. Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀, ayé yóò bí àwọn òkú rẹ̀ lọ́mọ.

  19. Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́. Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.

  20. “Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà; àwọn tó ń bá ọ jà yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé.

  21. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ kì yóò rí wọn. Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́ yóò dàbí ohun tí kò sí.

  22. Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù; Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.

  23. Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò, ìwọ Israẹli kékeré, nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,” ni Olúwa wí, olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.

  24. “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú. Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara, àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,

  25. Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀ bí ọfà láti fi pa irọ́; kì í ṣe nípa òtítọ́ ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn; wọn kò sì náání mi, ní Olúwa wí.