Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Warfare of Saints

107 ẹsẹ · 73 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi yóò sì fi ìràwọ̀ òwúrọ̀ fún un.

  2. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀; èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn angẹli rẹ̀.

  3. Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun, òun ni èmi ó fi ṣe ọ̀wọ́n nínú tẹmpili Ọlọ́run mi, òun kì yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ mọ́, èmi ó sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sí i lára, àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, tí i ṣe Jerusalẹmu tuntun, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi wá: àti orúkọ tuntun ti èmi tìkára mi.

  4. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi, bí èmi pẹ̀lú ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.

  5. Wọ́n sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn náà, àti nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn, wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀mí wọn àní títí dé ikú.

  6. Dragoni náà sì bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn irú-ọmọ rẹ̀ ìyókù jagun, tí wọ́n ń pa òfin Ọlọ́run mọ̀, tí wọn sì di ẹ̀rí Jesu mú, Ó sì dúró lórí iyanrìn Òkun.

  7. Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí; èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi.