Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Christ Jesus

607 ẹsẹ · 25 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Peteru sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.

  2. ṣùgbọ́n Jesu yíjú padà sí wọn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, ẹ má sọkún fún mi, ṣùgbọ́n ẹ sọkún fún ara yín, àti fún àwọn ọmọ yín.

  3. Nítorí kíyèsi i, ọjọ́ ń bọ̀ ní èyí tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Ìbùkún ni fún àgàn, àti fún inú tí kò bímọ rí, àti fún ọmú tí kò fún ni mu rí!’

  4. Nígbà náà ni “ ‘wọn ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Yí lù wá!” Sí àwọn òkè ńlá, “Bò wá mọ́lẹ̀!” ’

  5. Nítorí bí wọn bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí sára igi tútù, kín ni a ó ṣe sára igi gbígbẹ?”

  6. Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà?

  7. Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwa ṣe ni à ń jẹ, ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.”

  8. Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jesu tìkára rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ.

  9. Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n.

  10. Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kín ni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?” Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro.

  11. Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kileopa, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sá à ni ìwọ ní Jerusalẹmu, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?”

  12. Ó sì bi wọ́n pé, “Kín ni?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jesu ti Nasareti, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn,

  13. àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélébùú.

  14. Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Israẹli ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹta tí nǹkan wọ̀nyí ti ṣẹlẹ̀.

  15. Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá yà wá lẹ́nu,

  16. nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn angẹli tí wọ́n wí pé, ó wà láààyè.

  17. Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí, ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni wọn kò rí.”

  18. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́,

  19. Ṣùgbọ́n àyà fò wọ́n, wọ́n sì wárìrì, wọ́n ṣe bí àwọn rí ẹ̀mí kan.

  20. Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí èròkerò fi ń sọ nínú ọkàn yín?

  21. Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkára mi ni! Ẹ dì mímú kí ẹ wò ó nítorí tí iwin kò ní ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.”

  22. Ó sì wí fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé: kí Kristi jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ọjọ́ kẹta kúrò nínú òkú,

  23. àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀-èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu lọ.

  24. Ṣùgbọ́n Jesu kò gbé ara lé wọn, nítorí tí ó mọ gbogbo ènìyàn.

  25. Òun kò sì nílò ẹ̀rí nípa ènìyàn, nítorí tí o mọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ènìyàn.