Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Christ Jesus

607 ẹsẹ · 25 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Kì í ṣe fún èyíkéyìí ó fèsì, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí ogun Olúwa ni mo wá nísinsin yìí.” Nígbà náà ni Joṣua sì wólẹ̀ ní iwájú u rẹ̀ ní ìbẹ̀rù, ó sì bi í léèrè, “Kí ni Olúwa ní í sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?”

  2. Olórí ogun Olúwa sì dá a lóhùn pé, “Bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé ibi tí ìwọ dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀.

  3. Ọlọ́run Israẹli ni, àpáta Israẹli sọ fún mi pé, ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

  4. Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’

  5. Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀, àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?

  6. Àwọn ọba ayé péjọpọ̀ àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀ sí Olúwa àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.

  7. Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já, kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”

  8. Béèrè lọ́wọ́ mi, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ, òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.

  9. Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”

  10. Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà; kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé! Kí ọba ògo le è wọlé.

  11. Ta ni ọba ògo náà? Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le, Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.

  12. Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà; kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo le è wọlé wá.

  13. Ta ni Ọba ògo náà? Olúwa àwọn ọmọ-ogun Òun ni Ọba ògo náà. Sela.

  14. Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi mo ní òye àti agbára.

  15. Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára.

  16. Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso, àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.

  17. Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé, “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’

  18. Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì, mú kí etí wọn kí ó wúwo, kí o sì dìwọ́n ní ojú. Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran, kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀, kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn, kí wọn kí ó má ba yípadà kí a má ba mú wọn ní ara dá.”

  19. Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára, ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa.

  20. Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa. Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí, tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,

  21. ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní, pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu fún àwọn aláìní ayé. Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀, pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.

  22. Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀ àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.

  23. “Èmi, Olúwa, ti pè ọ́ ní òdodo, Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú. Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà

  24. láti la àwọn ojú tí ó fọ́, láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.

  25. Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá rẹ wà èyí tí mo fi lé e lọ? Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mi ni mo tà ọ́ fún? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́; nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ.