Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sin

210 ẹsẹ · 120 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i; Ọlọ́run Jakọbu kò sì kíyèsi i.”

  2. Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́ ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.

  3. Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ.

  4. Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí; dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi.

  5. Kí ó sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburú kan bá wà nínú mi kí ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.

  6. Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn.

  7. Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa; jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan, jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí;

  8. jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú, àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;

  9. a ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa,

  10. da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa, a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà,”

  11. Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra, ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i,

  12. Ojú ìgbéraga, ahọ́n tó ń parọ́ ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,

  13. ọkàn tí ń pète ohun búburú, ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà,

  14. ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan.

  15. Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi mo kórìíra ìgbéraga àti agídí, ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

  16. Èrè olódodo ń mú ìyè wá fún wọn, ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn.

  17. Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere.

  18. Òdodo a máa gbé orílẹ̀-èdè lékè, ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ.

  19. Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.

  20. Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.

  21. Ta ni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́, mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?

  22. Ojú tí ó gbéga àti ọkàn ìgbéraga, ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ẹ̀ṣẹ̀ ni!

  23. Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.

  24. Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò ṣe rere, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà.

  25. Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọn síbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn;