Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sin: Tempt others to

8 ẹsẹ · 120 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Tempt others to

  1. Nígbà tí obìnrin náà rí i wí pé èso igi náà dára fún oúnjẹ àti pé, ó sì dùn ún wò, àti pé ó ń mú ni ní ọgbọ́n, ó mú díẹ̀ níbẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Ó sì mú díẹ̀ fún ọkọ rẹ̀, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.

  2. “Èmi ti gbé ọ ga láti inú erùpẹ̀ wá, mo sì fi ọ́ ṣe olórí Israẹli ènìyàn mi, ṣùgbọ́n ìwọ sì rìn ní ọ̀nà Jeroboamu, ó sì mú kí Israẹli ènìyàn mi dẹ́ṣẹ̀, láti mú mi bínú nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  3. (Kò sí ẹnìkan bí Ahabu tí ó ta ara rẹ̀ láti ṣe búburú níwájú Olúwa, ẹni tí Jesebeli aya rẹ̀ ń tì.

  4. Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn.

  5. Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa; jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan, jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí;

  6. jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú, àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;

  7. a ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa,

  8. da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa, a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà,”