Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Repentance

343 ẹsẹ · 65 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.

  2. Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kurukuru, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀. Padà sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ padà.”

  3. “Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là, ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé; nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn.

  4. “Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ, fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀.

  5. Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i; ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.

  6. Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀. Jẹ́ kí ó yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì ṣàánú fún un, àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjì.

  7. Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́: “Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.

  8. “Olùdáǹdè yóò wá sí Sioni, sí àwọn tí ó wà ní Jakọbu tí ó ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí.

  9. Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi nítorí Olúwa ti fi àmì òróró yàn mí láti wàásù ìyìnrere fún àwọn tálákà. Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́ láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,

  10. láti kéde ọdún ojúrere Olúwa àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa, láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,

  11. Ǹjẹ́ ìwọ kò ha a pè mí láìpẹ́ yìí pé, ‘Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.

  12. Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá: “ ‘Yípadà, Israẹli aláìnígbàgbọ́,’ ni Olúwa wí. ‘Ojú mi kì yóò korò sí ọ mọ́, nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni Olúwa wí. Èmi kì yóò sì bínú mọ́ títí láé.

  13. Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ, ìwọ ti ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ ti wá ojúrere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì lábẹ́ gbogbo igikígi tí ó gbilẹ̀, ẹ̀yin kò gba ohun mi gbọ́,’ ” ni Olúwa wí.

  14. “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni Olúwa wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Sioni.

  15. “Èmi fúnra mi sọ wí pé, “ ‘Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó, kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrin kí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó.’ Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní ‘Baba mi’ o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn.

  16. “Tí ìwọ yóò bá yí padà, ìwọ Israẹli, padà tọ̀ mí wá,” ni Olúwa wí. “Tí ìwọ yóò bá sì mú ìríra rẹ kúrò níwájú mi, ìwọ kí ó sì rìn kiri.

  17. Tí ó bá jẹ́ lóòtítọ́ àti òdodo ni ìwọ búra. Nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láààyè, nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò di alábùkún fún nípasẹ̀ rẹ, àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo.”

  18. Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu: “Hú gbogbo ilẹ̀ tí ẹ kò lò rí, kí o má sì ṣe gbìn sáàrín ẹ̀gún.

  19. Kọ ara rẹ ní ilà sí Olúwa, kọ ọkàn rẹ ní ilà, ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú mi yóò ru jáde yóò sì jó bí iná, nítorí ibi tí o ti ṣe kì yóò sí ẹni tí yóò pa á.

  20. Ìwọ Jerusalẹmu, mú búburú kúrò lọ́kàn rẹ kí o sì yè. Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò mú èrò búburú wà ní ọkàn rẹ?

  21. Ìwọ Jerusalẹmu, gba ìkìlọ̀, kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro, tí kò ní ní olùgbé.”

  22. Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ẹ dúró sí ìkóríta, kí ẹ sì wò, ẹ béèrè fún ọ̀nà àtijọ́, ẹ béèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ rìn nínú rẹ, ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rìn nínú rẹ̀.’

  23. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Tún àwọn ọ̀nà yín ṣe, èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ gbé ilẹ̀ yìí.

  24. Bí ẹ̀yin bá tún ọ̀nà yín àti iṣẹ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ sì ń bá ara yín lò ní ọ̀nà tó tọ́.

  25. Nígbà náà ni èmi yóò jẹ́ kí ẹ gbé ìbí yìí, nílẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín títí láé.