Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Repentance: Danger of neglecting

8 ẹsẹ · 65 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Danger of neglecting

  1. Nígbà náà ni Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìlú tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ wí, nítorí wọn kò ronúpìwàdà.

  2. Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Korasini, ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú yín ní a ṣe ni Tire àti Sidoni, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà ti pẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.

  3. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tire àti Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín.

  4. Àti ìwọ Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run? Rárá, a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sodomu, òun ìbá wà títí di òní.

  5. Lóòótọ́ yóò sàn fún ilẹ̀ Sodomu ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ìwọ lọ.”

  6. Mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin pẹ̀lú ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.

  7. Mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.”

  8. Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte ìpọ́njú, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.