Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Repentance: Commanded to all by God

4 ẹsẹ · 65 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Commanded to all by God

  1. “Nítorí náà, ilé Israẹli, èmi yóò da yín lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá ṣe rí ni Olúwa Olódùmarè wí. Ẹ yípadà! Kí ẹ si yí kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ìrékọjá kì yóò jẹ́ ọ̀nà ìṣubú yín.

  2. Ẹ kọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti ẹ ti dá sílẹ̀, kí ẹ sì gba ọkàn àti ẹ̀mí tuntun. Nítorí kí ló fi máa kú, ilé Israẹli?

  3. Nítorí pé inú mi kò dùn sí ikú ẹnikẹ́ni ni Olúwa Olódùmarè wí. Nítorí náà, ẹ yípadà kí ẹ sì yè!

  4. Pẹ̀lúpẹ̀lú ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí fojú fò dá; ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà.