Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Repentance

343 ẹsẹ · 65 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Láti ọjọ́ àwọn baba wá ni ẹ̀bi wa ti pọ̀ jọjọ títí di ìsinsin yìí. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwa àti àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa ni a ti sọ di ẹni idà, ẹni ìgbèkùn, ìkógun àti ẹni ẹ̀sín lọ́wọ́ àwọn àjèjì ọba, bí ó ti rí lónìí.

  2. “Ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí, fún ìgbà díẹ̀, ni a ti fi oore-ọ̀fẹ́ fún wa láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa wá láti sálà, àti láti fi èèkàn fún wa ni ibi mímọ́ rẹ̀, nítorí kí Ọlọ́run kí ó lè mú ojú wa mọ́lẹ̀, kí ó sì tún wa gbé dìde díẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn wa.

  3. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa jẹ́ ẹrú, Ọlọ́run wa kò fi wa sílẹ̀ nínú ìgbèkùn wa. Ó ti fi àánú hàn fún wa ni iwájú àwọn ọba Persia: Ó ti fún wa ní ìgbé ayé tuntun láti tún odi ilé Ọlọ́run wa mọ, kí a sì tún àwókù rẹ̀ ṣe, ó sì fi odi ààbò fún wa ní Juda àti ní Jerusalẹmu.

  4. “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, kí ni àwa yóò wí lẹ́yìn èyí? Nítorí tí àwa kọ àṣẹ rẹ sílẹ̀

  5. èyí tí ìwọ ti pa fún wa láti ẹnu àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, nígbà ti ìwọ wí pé, ‘Ilẹ̀ náà ti ẹ̀yin ń wọ̀ lọ láti gbà n nì jẹ́ ilẹ̀ aláìmọ́ tó kún fún ẹ̀gbin àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, nípa ṣíṣe ohun ìríra àti híhu ìwà èérí ti kún ún láti ìkángun kan dé èkejì.

  6. Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní ìyàwó tàbí kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó. Ẹ má ṣe dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn nígbàkígbà kí ẹ̀yin kí ó sì le lágbára, kí ẹ sì le máa jẹ ire ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le fi í sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín gẹ́gẹ́ bí ogún ayérayé.’

  7. “Ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa jẹ́ àyọríṣí iṣẹ́ búburú wa àti ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wa, síbẹ̀, Ọlọ́run wa, ìjìyà ti ìwọ fún wa kéré si ìjìyà tí ó yẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti a dá, ìwọ sì fún wa ní àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù bí èyí.

  8. Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa tún yẹ̀ kúrò nínú àṣẹ rẹ, kí a sì máa ṣe ìgbéyàwó papọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣe onírúurú ohun ìríra báyìí? Ṣe ìwọ kò ní bínú sí wa láti pa wá run tí kì yóò sẹ́ ku ẹnikẹ́ni tí yóò là?

  9. Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ìwọ jẹ́ olódodo! Àwa ìgbèkùn tí ó ṣẹ́kù bí ó ti rí lónìí. Àwa dúró níwájú rẹ nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nítorí èyí ẹnikẹ́ni nínú wa kò lè dúró níwájú rẹ”.

  10. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá yípadà sí mi, tí ẹ bá sì pa àṣẹ mi mọ́, nígbà náà bí àwọn ènìyàn yín tí a kó ní ìgbèkùn tilẹ̀ wà ní jìnnà réré ìpẹ̀kun ọ̀run, èmi yóò kó wọn jọ láti ibẹ̀, èmi yóò sì mú wọn wá, sí ibi tí èmi ti yàn bí i ibùgbé fún orúkọ mi.’

  11. “Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un, tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,

  12. bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ,

  13. nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láìní àbàwọ́n, àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù.

  14. Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró. Bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,

  15. Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì ṣe ojúrere rẹ̀, o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀, òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn.

  16. Ó wá sọ́dọ̀ ènìyàn ó sì wí pé, ‘Èmi ṣẹ̀, kò sì ṣí èyí tí o tọ́, mo sì ti yí èyí tí ó tọ́ po, a kò sì san ẹ̀san rẹ̀ fún mi;

  17. Ọlọ́run ti gba ọkàn mi kúrò nínú lílọ sínú ihò, ẹ̀mí mi yóò wà láti jẹ adùn ìmọ́lẹ̀ ayé.’

  18. “Nítorí pé ẹnìkan ha lè wí fún Ọlọ́run pé, èmi jẹ̀bi, èmi kò sì ní ṣẹ̀ mọ́?

  19. Èyí tí èmi kò rí ìwọ fi kọ́ mi bi mo bá sì dẹ́ṣẹ̀ èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

  20. Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́, ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedédé.

  21. Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi, mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú.”

  22. Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí wọn yóò sì yípadà sí Olúwa, àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,

  23. Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere; wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.

  24. Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.

  25. Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.